Aderounmu Kazeem
Mọnde, ọjọ Aje to n bọ yii ni ijọba ipinlẹ Eko ti kede wi pe ki gbogbo awọn ọmọleewe pada sẹnu ẹkọ wọn.
Kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Eko, Arabinrin Fọlaṣade Adefisayọ lo sọrọ ọhun. Bakan naa lo sọ pe o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ bi eto ẹkọ ṣe n ṣe segesege ninu ọdun yii, pẹlu bi awọn ọmọleewe ko ṣe ni kilaasi igbẹkọ fun ọpọ igba ninu ọdun 2020 yii.
O fi kun ọrọ ẹ pe, awọn ti wọn je akẹkọọ ti wọn n gbe ninu ọgba ileewe, iyen awọn Bọoda gbọdo ti pada sile ẹkọ lọjọ Aiku, Sannde yii. Nigba ti gbogbo awọn akẹkọọ yooku yoo pada sẹnu ẹkọ wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji oṣu kọkanla ọdun yii.
Kọmiṣanna yii ti waa rọ gbogbo akẹkọo pata lati kọju mọ iwe wọn, bẹẹ lo sọ pe oun ni ireti wi pe akude kankan ko tun ni i ba eto ẹkọ mọ titi ti saa tuntun yii yoo fi pari