Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ijọba ti fun awọn to fara gba ninu wahala to ṣẹlẹ lasiko tawọn ileewe n fa wahala ọrọ lilo hijaabu lawọn ileewe to wa ni Kwara lẹbun owo.
Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi (CAN) ẹka ti ipinlẹ Kwara, ni ijọba ipinlẹ Kwara ti mu ileri rẹ ṣẹ pẹlu bo ṣe peṣe owo gba, ma binu, fawọn olori ile ẹkọ (Missionary) tawọn janduku ṣe akọlu si awọn ile ijọsin wọn lakooko rogbodiyan to waye laaarin awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi lori lilo hijaabu awọn akẹkọọ Musulumi nile ẹkọ ijọba to jẹ ti (Missionary).
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi nipinlẹ Kwara, Sina Ibiyẹmi, lo fọrọ naa lede, o lu ijọba Kwara lọgọ ẹnu lori bo ṣe mu ẹjẹ rẹ ṣẹ.
O ni ijọba fun awọn oludasilẹ ileejọsin ti wọn ba dukia wọn jẹ lowo, wọn si tun san gbogbo owo itọju awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ naa.
A oo ranti pe ni nnkan bii oṣu meloo kan sẹyin ni gbọn mi si i, omi o to o waye, laarin ẹlẹsin Kristiẹni ati Musulumi, nigba ti wọn sọ pe awọn alasẹ ile ẹkọ to jẹ ti awọn Onigbagbọ yii (Missionary) kọ jalẹ pe awọn ko fi aaye gba akẹkọọ Musulumi lati wọ hijaabu lawọn ile ẹkọ wọn to wa ni Ilọrin. Ọrọ yii da wahala silẹ, o si mu ki ijọba ti ile ẹkọ mẹwaa tọrọ kan ni ilu Ilọrin pa, ko too di pe gbogbo aawọ naa pada di ohun igbagbe.
Ijọba jẹẹjẹ iranwọ fawọn to fara ko ninu wahala naa, to si ti mu ileri rẹ ṣẹ bayii.