Ijọba fẹẹ fiya jẹ olukọ, akẹkọọ atawọn obi to lọmọ lawọn ileewe kan nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori ti awọn ileewe kan lọwọ ninu magomago idanwo Wayẹẹki fawọn akẹkọọ wọn, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti pinnu lati da sẹria fawọn akẹkọọ ileewe ọhun, iya ọhun ko si

yọ awọn olukọ atawọn obi to lọmọ nileewe naa silẹ.

Kọmiṣanna feto ẹkọ ati imọ sayẹnsi nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Abiọdun Abdu-Rahman lo fidi iroyin yii mulẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, laipẹ yii lajọ to n ṣakoso idanwo aṣejade iwe girama, iyẹn West African Examinations Council (WAEC) fofin de awọn ileewe kan, wọn ni awọn ko ni i jẹ ki wọn ṣedanwo Wayẹẹki fun odidi ọdun meji gbako nitori ti wọn ran awọn akẹkọọ wọn lọwọ ninu idanwo naa ki wọn too ṣaṣeyege.

Amọ ṣaa, eto ijiya ti ajọ to n mojuto idanwo ileewe girama yii ṣe ko di awọn akẹkọọ to wa nipele aṣekagba lọwọ lati ṣẹdanwo Wayẹẹki laarin ọdun mejeeji ọhun, o kan jẹ pe ileewe mi-in lagbegbe ileewe wọn ni wọn yoo ko gbogbo wọn lọ lati lọọ ṣedanwo naa.

Ṣugbọn ni ti ijọba ipinlẹ Ọyọ, ijiya tiwọn ko yọ ẹnikẹni silẹ, wọn yoo fiya jẹ awọn alaṣẹ ileewe to lọwọ ninu magomago idanwo naa, wọn yoo si tun fiya jẹ awọn akẹkọọ funra wọn, ijọba yoo si fiya jẹ awọn obi wọn pẹlu.

Ọjọgbọn Abdu-Rahman sọ pe igbesẹ ti awọn gbe yii ki i ṣe lati ṣafihan iwa ọdaju, bi ko ṣe lati fopin si iwa magomago laarin awọn ileewe to jẹ tijọba atawọn ileewe aladaani gbogbo to wa ni ipinlẹ naa pẹlu.

Leave a Reply