Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ti wọn n ṣe omi inu ọra, omi inu ike, awọn onilailọọọnu atawọn mi-in ti wọn n ṣe awọn nnkan eelo tawọn eeyan n lo tan ti wọn n ju sọnu yoo bẹrẹ si i sanwo diẹdiẹ sapo ijọba ipinlẹ Ogun lati ọdun to n bọ lọ, gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si imọtoto ayika nipinlẹ yii ṣe sọ.
Kọmiṣanna fun ayika nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Abiọdun Abudu-Balogun, lo sọ ọrọ yii di mimọ lọsẹ to kọja, lasiko to n ṣalaye lori aba iṣuna ọdun 2021, nile igbimọ aṣofin ipinlẹ yii.
Ọga ileeṣẹ imọtoto naa ṣalaye pe awọn nnkan bii ike omi, bii lailọọọnu atawọn nnkan bẹẹ lo n di koto idominu lọpọ igba, ti wọn si tun maa n kun oju titi kaakiri. Bẹẹ, ewu ni wọn jẹ fun alaafia awọn eeyan, eyi to fa a tijọba fi n nawo ribiribi lori wọn lati ko wọn kuro.
Lati le ran ijọba lọwọ ninu inawo naa ni Ọnarebu Abiọdun sọ pe o fa a ti awọn ileeṣẹ wọnyi yoo fi maa sanwo diẹdiẹ si apo ijọba. O ni kekere lowo ti wọn yoo maa san latọdun to n bọ naa, bi a ba wo iye ti ijọba n na lori wahala awọn ike ati lailọọnu yii.
O fi kun un pe ijọba yoo ṣe awọn koto idaminu sawọn ọja ati agbegbe kaakiri si i, bẹẹ ni wọn yoo la awọn koto nla ti wọn n pe ni kanaali (Canal), ki ọna ati da ẹgbin nu tun le rọrun si i. Balogun pe fun ifọwọsowọpọ awọn ileeṣẹ tọrọ kan, o ni ki wọn ma ri igbesẹ yii bii irẹnijẹ, ṣugbọn ki wọn gba a bii ọna kan lati ran ilu lọwọ latara iṣẹ wọn ti wọn n ṣe.