Oluyinka Soyemi
Lati din wahala ti araalu n koju lori ọrọ konilegbele ti arun Koronafairọọsi da silẹ ku, ijọba ipinlẹ Eko ti fi kun iye wakati tawọn ọlọja yoo maa fi taja kaakiri ipinlẹ naa bayii.
Kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati agbegbe, Ọmọwe Wale Ahmed, lo kede ọrọ naa lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ahmed ni awọn ọlọja ti lanfaani lati taja laarin aago mẹjọ aarọ si mẹfa irọlẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu lo si gbe igbesẹ naa lati tu awọn eeyan lara.
O waa ni ko si ayipada lori ọjọ tawọn ọlọja yoo maa patẹ, eyi to jẹ ọjọ Tusidee, Tọsidee ati Satide fawọn to n ta ounjẹ, nigba to Mọnde, Wẹsidee ati Furaidee wa fawọn to n taja mi-in.