Stephen Ajagbe, Ilorin
Lẹyin ti oṣu mẹfa akọkọ tijọba fi jawee gbele-ẹ fawọn alaga ijọba ibilẹ mẹrindinlogun nipinlẹ Kwara pe, Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq tun kede pe oun ti fi oṣu mẹfa mi-in kun un fun wọn.
Ninu atẹjade kan lati ọọfiisi akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, lo ti sọ pe “Lonii ni gomina buwọ lu igbele oṣu mẹfa mi-in fun awọn alakooso ijọba ibilẹ naa. Ijọba ṣe bẹẹ ni ibamu pẹlu aba tileegbimọ aṣofin Kwara da lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2019.”
O ni igbesẹ naa pọn dandan nitori iwadii ti EFCC n ṣe lọwọ lori ẹsun kiko owo ilu jẹ ti wọn fi kan awọn adari kansu naa.
Bo tilẹ jẹ pe awọn alaga kansu ọhun ti dara pọ mọ ẹgbẹ APC, iyẹn ko da ijọba tabi EFCC duro lati tẹsiwaju ninu iwadii wọn.
Igbagbọ awọn eeyan ni pe bi wọn ṣe dara pọ mọ ẹgbẹ to n ṣe ṣakoso lọwọ ni Kwara tumọ si pe ẹṣẹ wọn ti parẹ tabi pe ijọba ti foriji wọn. Ṣugbọn wọn ni ko ri bẹẹ rara, ẹlẹṣẹ kan ko ni i lọ lai jiya. Ati pe ọwọ EFCC lọrọ naa wa, ijọba ko laṣẹ lori rẹ mọ.
Ṣugbọn awọn alaga kansu naa ti ni ki i ṣe nitori ati ri ojurere gomina lawọn ṣe dara pọ mọ APC o, ohun to wu awọn lọkan ni igbesẹ tawọn gbe.
Alaga ALGON, Ọnarebu Joshua Ọmọkanye Jalala, to gbẹnu sọ fun wọn ni, gbogbo ariwo to n lọ nigboro nipa bi ijọba ṣe fi oṣu mẹfa kun ifidimọle awọn ko jẹ ohun tuntun ninu oṣelu. Iwadii ni wọn n ṣe, o si le dopin ki oṣu mẹfa naa too pari.
O ni fun idi eyi, ko si ohun to n min awọn rara, awọn ko si kabaamọ pe awọn darapọ mọ ẹgbẹ APC, ati pe ki i ṣe ohun tawọn maa jẹ lawọn n wa kiri bi ko ṣe ifẹ lati kopa ninu idagbasoke ilu.