Faith Adebọla, Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede iyansipo Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, gẹgẹ bii alaga igbimọ tijọba fa iṣẹ le lọwọ lati maa ṣamojuto awọn gareeji ati onimọto nipinlẹ Eko.
Bakan naa ni wọn kede ifofinde ẹgbẹ onimọto, National Union of Road Transport Workers (NURTW), ati gbogbo igbokegbodo wọn jake-jado ipinlẹ naa.
Ikede yii wa ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ọgbọn inu, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ, fi lede laaarọ Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii. O ni ijọba gbe igbesẹ yii ki lọgbọlọgbọ to n waye ninu ẹgbẹ NURTW ma baa da iṣu-ata-yan-an-yan-an silẹ nipinlẹ Eko, paapaa laarin awọn onimọto, ati lati dena awọn janduku ti wọn le fẹẹ fi rogbodiyan boju lati ṣiṣẹẹbi.
Yatọ si MC Oluọmọ, ijọba tun yan Kọmiṣanna ọlọpaa ana nipinlẹ Eko, AIG Hakeem Odumosu, to ti fẹyinti gẹgẹ bii aṣoju ijọba laarin igbimọ ẹlẹni mẹẹẹdọgbọn naa.
Ọpọ awọn ọmọ igbimọ MC Oluọmọ lasiko to fi wa nipo alaga ẹgbẹ onimọto nijọba tun yan sinu igbimọ alamoojuto gareeji yii. Lara wọn ni Alaaji Sulyman Ọjọra, igbakeji alaga, Alaaji Mukaila Runsewe, ati Alaaji Mustapha Adekunle.
Ṣaaju iṣẹlẹ yii ni MC Oluọmọ ti sọ pe awada kẹrikẹri lawọn ti wọn tun lawọn yọ oun patapata nipo alaga ẹgbẹ onimọto l’Ekoo, n ṣe, tori oun ti fi ẹgbẹ ọhun silẹ tipẹ, ati pe lẹyin lilọ oun, ẹgbẹ naa ko tun le rọwọ mu nipinlẹ Eko mọ, gbogbo anfaani ti ẹgbẹ ọhun ni lo ti sọnu, wọn o si le ri i he.
MC Oluọmọ sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin yii, nigba to n fesi fun iweeroyin The Nation lori yiyọ ti igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ naa yọ ọ nipo patapata, ti wọn si tu gbogbo awọn ọmọ igbimọ rẹ ka l’Ekoo.
Akinsanya ni: Lara ijọba palapala ti aarẹ ẹgbẹ naa n ṣe ta a ti n ṣaroye nipa ẹ tipẹ lẹ ri yẹn. Ko si laakaye kankan ninu bi wọn ṣe lawọn tu ile ka yii. Amọ ṣa, a fẹ kawọn eeyan mọ pe a o ni wahala kan pẹlu igbimọ alakooso apapọ ẹgbẹ NURTW o, aarẹ ẹgbẹ naa niṣoro wa.
“Ẹ jẹ ka maa wo bi ẹni ti wọn lawọn ṣẹṣẹ yan rọpo ṣe maa ṣakoso. Ijọba ti so ẹgbẹ naa rọ l’Ekoo, ṣe awọn alakooso apapọ yii fẹẹ sọ pe awọn lagbara ju ijọba ipinlẹ Eko lọ ni?
“Eyi ti wọn waa ṣẹṣẹ n kede pe awọn yọ wa nipo lẹyin ti a ti la o ba wọn ṣẹgbẹ mọ, ti a si ti yọpa yọsẹ ninu ẹgbẹ wọn yii fihan pe alawada kẹrikẹri lasan ni wọn, tori o paayan lẹrin-in.”
Ọrọ naa ko yatọ si ti Agbẹnusọ rẹ lori eto iroyin. Ọgbẹni Jimọh Buari sọ f’ALAROYE nigba ta a pe e lori foonu lọjọ Wẹsidee ọhun, o ni yiyọ ti wọn lawọn yọ MC Oluọmọ patapata, awọn si tu ile ka yii, ko nitumọ, ọrọ awada ni.
O ni ọga oun ko ni igbesẹ kan to fẹẹ gbe lori ọrọ yii mọ, tori o ti kuro ninu ẹgbẹ naa, ẹgbẹ yii ko si tun le rọwọ mu l’Ekoo mọ, gbogbo anfaani to si n jẹ tẹlẹ ti dopin.
“Ọga mi (MC Oluọmọ) ti kuro ninu ẹgbẹ NURTW lati ọjọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun 2022, a si kede faye gbọ lọjọ naa l’Agege. Bawo waa ni awọn ara Abuja ti Baruwa ko sodi ṣe maa lawọn yọ ẹni to ti loun o ba wọn ṣe mọ danu. Ko yatọ si keeyan loun le ọmọọṣẹ oun danu lẹyin oṣu kan tọmọọṣẹ naa ti kọwe fipo silẹ. O paayan lẹrin-in, ko si mọgbọn dani rara.”
Bẹẹ ni Buari sọ.