Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ikilọ ti lọ setigbọọ awọn tiṣa nipinlẹ Ogun, pe ki wọn yee lu akẹkọọ nilukuku, kaka bẹẹ, ki wọn wa ọna mi-in ti wọn le fi ba ọmọ wi ti ko si ni i pa ọmọ naa lara.
Kọmiṣanna eto ẹkọ, Sayẹnsi ati Imọ ẹrọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, lo ṣe ikilọ yii lasiko to pade pẹlu awọn alaṣẹ atawọn olukọ nileewe Adeoye International School, eyi to wa ni Iyẹsi-Ọta, nibi ti tiṣa obinrin kan, Abilekọ Taiwo Ọdunọla, ti lu ọmọ ọdun mẹta bii ejo aijẹ nitori ọmọ naa kọ lati kọwe gẹgẹ bi aṣẹ tiṣa rẹ.
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, ni Abilekọ Ọdunọla lu ọmọ naa ti wọn pe orukọ ẹ ni Chizaram, lilu naa pọ to jẹ niṣe ni ẹsẹ ọmọde naa mejeeji le.
Iya ọmọ yii, Elizabeth Ebere, tilẹ sọ pe niṣe lọmọ naa bẹrẹ si i gbona nigba to ti ileewe de lọjọ naa, bo si ṣe n gbona lala niyẹn titi di ọjọ keji, to jẹ ileewosan loun pada gbe e lọ.
O loun fẹjọ tiṣa naa sun ọga ileeewe yii, ṣugbọn iyẹn naa ko ja a kunra, afigba toun gbe iṣẹlẹ naa soju opo Fesibuuku, to de etiigbọ ijọba lawọn alaṣẹ ileewe naa too mọ ọn lọran.
Nigba tiṣẹlẹ naa de etiigbọ ijọba ipinlẹ Ogun ni Kọmiṣanna eto ẹkọ da si i, to si fi ofin lelẹ pe lilu ọmọ lai nidii gbọdọ lọ sokun igbagbe, nitori ilukulu ko ni kọmọ mọwe, yoo wulẹ ko ibẹru sọkan ọmọ naa ni. O ni ko ni i jẹ ki ọkan ọmọ papọ, bẹẹ ni k’Ọlọrun ma jẹ ka ri Eṣu, eeyan le lu ọmọ lẹgba nigba mi-in ko ja siku, nigba to ba gba odi lara akẹkọọ ọhun.
Fun idi eyi, Arigbabu sọ pe ijọba ipinlẹ Ogun ko ni i gba ki tiṣa maa lu ọmọ nilukulu, bẹẹ lo ni inu oun ko dun si iṣẹlẹ to waye nileewe Adeoye yii rara.
Kọmiṣanna gba awọn alaṣẹ ileewe nimọran pe ki wọn maa ṣe idanilẹkọọ fawọn tiṣa wọn loore-koore, ti wọn yoo fi maa mọ ọna teeyan le gba fa oju ọmọ mọra lati kẹkọọ, lai ṣẹṣẹ nilo lati lu u bii ẹwurẹ.
Awọn alaiṣẹ ileewe yii ti tọrọ aforiji lọwọ awọn obi ọmọ ti tiṣa wọn lu, wọn si ti ni ki tiṣa naa lọọ rọọkun nile na.