Ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣi ọja Ṣáṣá pada

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Lẹyin nnkan bii ọsẹ meji tí ìjọba ti ti ọja Ṣàṣà pa nitori laasigbo to waye níbẹ, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣi ọja Ṣáṣá, n’Ibadan, pada.

Gomina Makinde funra rẹ̀ lo kede igbesẹ naa lỌjọ́ Iṣẹ́gun, lasiko to n ṣepade pẹlu awọn aṣáájú Yoruba ati Hausa agbegbe Ṣáṣá nileegbimọ awọn lọba lọba to wa ninu ọgbà Sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa l’Agodi, n’Ibadan lonii.

Ta o ba gbagbe, lọsẹ to lọ lọhun-un ni Gomina Makinde ti ọja Ṣáṣá pa nitori laasigbo to bẹ silẹ laarin awọn Yorùbá atawọn Hausa inu ọja naa lẹyin ti alábàárù kan tó jẹ Hausa lù Yoruba kan lóòka pa.

Nigba to n ṣi ọja naa pada ninu ipade pẹlu awọn aṣáájú ẹ̀yà mejeeji ni Ṣáṣá, Gomina Makinde sọ pé nítorí ìpọ́njú to n ba àwọn ontaja ọja naa latari títì tí ìjọba ti i pa lo jẹ kí oun gbà lati ṣí i pada gẹgẹ bi ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òǹtàjà níbẹ̀ ṣe n bẹ oun lati ọjọ yii pe kí wọn gba awọn laye láti máa ba kárà-kátà awọn lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti emi pẹlu awọn gomina ẹgbẹ mi ti wọn wa lati ilẹ Hausa ṣabẹwo sí aafin Séríkí ati Baálẹ̀ Ṣáṣá, mo ṣakiyesi pe oju gbogbo awọn ti mo ri lo kọ́rẹ́ lọ́wọ́, mo sí mo pé nítorí pé wọn kò ribi ṣe kárà-kátà wọn mọ ni kò jẹ́ kí inu wọn dùn.

“Gbogbo yin naa lẹ mọ pe nigba ti gbogbo ayé n ti ọja pa lasiko ti ajakalẹ arun Korona dojú ẹ gan-an, ijọba tiwa ko ti ọja pa nitori a mọ pé awọn kan wa to jẹ pe bi wọn kò bá ṣiṣẹ́ lojumọ, wọn kò ní í rí oúnjẹ ọjọ naa jẹ.

“Nitori bi eto ọrọ ajé wá ṣe rí lorileede yii lasiko yii, mo ti gbọ ohun tẹ ẹ wí, a sì máa ṣí ọja ṣáṣá ta a ti pa bayii, bayii.

“Lonii yìí náà ni máa sọ pé kí wọn lọọ fi kátakátà palẹ gbogbo idọti to wa nibe mọ tẹ ẹ sí máa bẹrẹ kárà-kátà yin pada ni Ṣáṣá.”

 

Leave a Reply