Ijọba ipinlẹ Ọyọ at’Ọṣun fẹẹ pawọ pọ ṣe ọna Ibadan s’Oṣogbo

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ajọsọ ọrọ ti waye laarin Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pẹlu akẹgbẹ ẹ nipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla, wọn si ti fẹnu ko lati jumọ ṣatunṣe ọna Ibadan siluu Oṣogbo.
Ọna ọhun, to jẹ tijọba apapọ lawọn ipinlẹ gbogbo to wa ni iha Iwọ-Oorun Guusu orileede (ilẹ Yoruba) n gba lọ si ipinlẹ Kwara.
Atẹjade ti Ọgbẹni Taiwo Adisa ti i ṣe Akọwe iroyin fun Gomina Makinde fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, fidi ẹ mulẹ pe adehun ti wa laarin awọn gomina mejeeji lati jọ tun ọna ọhun ṣe lai duro de ijọba apapọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ti fi igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe yii han sijọba apapọ.
Lati Iwo Road, n’Ibadan, la gbọ pe wọn yoo ti bẹrẹ ọna naa, titi deluu Oṣogbo, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun.
Gẹgẹ bi eto ti awọn Kọmiṣanna feto irinna ati iṣẹ ode ni ipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Dauda Kẹhinde Ṣangodoyin ati Ẹnjinnia Olurẹmi Ọmọwaiye, tipinlẹ Ọṣun jọ ṣe, ipinlẹ Ọyọ ni yoo ṣe ọna naa lati Iwo Road, n’Ibadan, de orita Ogunremako, niluu Lalupọn, nigba ti ijọba ipinlẹ Ọṣun yoo pari iyoku, bẹrẹ lati Lalupọn de Oṣogbo.
Odiwọn to le diẹ ni kilomita mọkandinlọgbọn (29.2km) ni abala ti ijọba Makinde yoo ṣe ninu ọna naa, nigba ti abala yooku ti ijọba Oyetọla yoo ṣe jẹ ọgọrin kilomita (80 km).

“Loootọ, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Gomina Makinde, nigba ti Gomina Oyetọla jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, ṣugbọn ọrọ oṣelu kọ lo wa nilẹ yii, iṣọkan laarin awa ijọba ilẹ Yoruba lo ṣe koko, fun anfaani awọn eeyan wa”, bẹẹ ni Ọmọwaiye ti i ṣe kọmiṣanna feto irinna ati iṣẹ ode ni ipinlẹ Ọṣun ṣe sọ lasiko asọyepọ ọrọ laarin awọn aṣoju ijọba ipinlẹ mejeeji lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Leave a Reply