Lati dena ki owo-oṣu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti maa pọ lọrun ijọba, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti pinnu lati bẹrẹ si i san owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ipinlẹ naa lati ọdun 2019 di asiko yii.
Ki eyi le baa ṣee ṣe lo mu ki ijọba fi kun owo ti wọn maa n ya sọtọ fun eleyii loṣooṣu. Ni bayii, miliọnu lọna igba o le lọgbọn (230m) si igba ati marundinlogoji (235) ni wọn ya sọtọ bayii.
Lẹyin ipade awọn alaṣẹ ipinlẹ naa to waye ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Kọmiṣanna fun eto iroyin, Dokita Wasiu Ọlatubọsun, ṣalaye ọrọ yii fawọn oniroyin.
Kọmiṣanna ni lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni igbimọ naa gbe aba kan dide lori bi ijọba yoo ṣe tete maa san owo-oṣu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ati ajẹmọnu wọn ni kete ti wọn ba ti kuro lẹnu iṣẹ.
Eyi lo mu ki wọn gbe igbimọ kan dide ti yoo ri si bi eyi yoo ṣe di siṣe. Lara awọn ọmọ igbimọ naa gẹge bi Ọlatubọsun ṣe sọ ni akọwe ijọba, olori awọn oṣiṣẹ, kọmiṣanna fun eto idajọ, kọmiṣanna fun eto isuna ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọlatubọsun ni lẹyin ti awọn igbimọ yii jabọ iṣẹ wọn ni awọn ya miliọnu lọna aadọta naira sọtọ lati mojuto awọn oṣiṣẹ ọba to ba fẹyinti laarin oṣu karun-un, ọdun 2019, si oṣu karun-un, ọdun 2023.
O fi kun un pe sisan owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ati ajẹmọnu awọn to ti fẹyinti jẹ ijọba Gomina Ṣeyi Makinde logun.