Ijọba ko awọn Hausa to n tọrọ baara kuro ni Sabo, n’Ibadan  

Faith Adebọla

Awọn ọkọ bọginni bọginni to jẹ tijọba nijọba ipinlẹ Ọyọ ko da silẹ ti wọn fi n ko awọn Hausa ti wọn maa n tọrọ baara ti wọn wa ni awọn ile pako to wa ni ọna Jẹmibẹwọn, Sabo, niluu Ibadan, kuro ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ti wọn si ko wọn lọ si aaye tuntun ti wọn ti pese fun wọn ni Ọjọọ, nijọba ibilẹ Akinyẹle, niluu Ibadan kan naa.

O ti to oṣu diẹ tijọba ipinlẹ Ọyọ ti n gbero ati ko awọn eeyan naa kuro nibi ti wọn wa yii. Ṣugbọn ni nnkan bii aago meje aarọ ọjọ Iṣẹgun ni wọn ko awọn ọkọ bọginni to jẹ tijọba atawọn taxi lọ sibi ti awọn Hausa to maa n tọrọ baara yii maa n gbe ni Sabo, ti wọn si ko wọn sinu ọkọ naa lati ko wọn lọ si ibi aaye tuntun ti wọn pese fun wọn, eyi to ni awọn ohun amayedẹrun bii ileewe, ileewosan ati ibi igbafẹ gbogbo.

Kọmiṣanna eto ayika nipinlẹ Ọyọ, Amofin Idowu Oyeleke, ẹni to dari awọn ikọ to n ko awọn eeyan naa ṣalaye pe o ti to ọjọ mẹta tijọba ti n gbe igbesẹ lati ko awọn eeyan ọhun kuro, ko too di pe wọn bẹrẹ igbesẹ naa lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

O fi kun un pe ikọ oun ati ti awọn AREWA pẹlu aṣoju awọn Hausa to n tọrọ baara yii lawọn ti kọkọ jọ ṣabẹwo si ibi aaye tuntun ti wọn n ko wọn lọ naa ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

       O ni gbogbo nnkan ti yoo mu aye dẹrun fun awọn eeyan naa lo wa nibi ti wọn ṣẹṣẹ ko wọn lọ yii.

Leave a Reply