Ijọba ko le sanwo oṣu iṣẹ tawọn olukọ yunifasiti ko ṣe fun wọn o – Gbajabiamila

Jọkẹ Amọri

Ọpọlọpọ awọn olukọ yunifasiti gbogbo lo lanu silẹ ti wọn o le pa a pade lọsẹ to kọja, nigba ti wọn ri i pe idaji owo-oṣu nijọba apapọ san fawọn. Ohun to mu eyi ya wọn lẹnu ni pe nigba ti wọn yoo pada sẹnu iṣẹ wọn, ki i ṣe adehun to wa laarin awọn ati ijọba niyẹn, ijọba ko sọ pe oun ko ni i san owo-oṣu wọn fun wọn. Ṣugbọn ni bayii, ijọba ni oṣu Kẹwaa ọdun ti da si meji ki wọn too pada sẹnu iṣẹ, iyẹn lo si ṣe jẹ ki awọn san idaji owo fun wọn, pe ti wọn ba ṣiṣẹ wọn lẹkun-un-rẹrẹ loṣu yii, wọn yoo gba owo-oṣu wọn lodidi.

Ọrọ yii bi awọn olukọ yuunifasiti ninu gan-an, ti awọn mi-in n sọ pe awọn ko ni i ṣiṣẹ, ti igbimo apaṣẹ ASUU ti n sare pe ipade pajawiri, o si jọ pe wahala mi-in yoo tun ṣẹlẹ laipẹ jọjọ. Ki ọrọ ma di wahala ni olori ileegibmọ aṣoju-ṣofin, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila, fi sare gbe atẹjade kan sita fawọn oniroyin lọjọ Aje, ọjọ Keje, oṣu yii, nibi to ti sọ fun gbogbo ilu idi ti ijọba apapọ ko fi ni i sanwo awọn olukọ to daṣẹ silẹ naa lodidi.

Gbajabiamila ni ninu ofin lọrọ naa wa, ki i ṣe adaṣe. O ni awọn ṣi n duro de Aarẹ Muhammadu Buhari, pe ko tilẹ wo ninu aanu ati ọla-nla rẹ, ko ṣiju aanu wo awọn olukọ yunifasiti yii, ko san aabọ-aabọ owo-oṣu ti awọn gbe ranṣẹ si i. Ọkunrin Gbaja yii fi kun ọrọ rẹ bayii pe:

“Ki i ṣe dandan ni ki ijọba apapọ sanwo oṣu fawọn oṣiṣe ni gbogbo asiko ti wọn ba fi yanṣẹlodi, nitori lati le dẹkun iru iwa bẹẹ,  ati ki iṣẹ ijọba ma daru leleyii ṣe wa bẹẹ. Ṣugbọn ijirẹbẹ oriṣiiriṣii ti n lọ lati le jẹ ki ijọba san aabọ diẹdiẹ ninu awọn owo-oṣu yii. Ẹni ti a n duro de bayii ni Aarẹ Buhari, ẹni to ti fihan ni gbogbo ọna pe oun ko ni i fara mọ inakunaa kan.

“Ki gbogbo nnkan ti awọn olukọ yunifasiti wọnyi beere fun too ṣee ṣe maa gba akoko, nitori ẹ ni ko ṣe gbọdọ si girigiri, tabi ikanju, wọn ko si gbọdọ tun da ija mi-in silẹ laarin awọn ati ijọba.” Bẹẹ ni olori ile aṣofin yii wi, pẹlu afikun pe nitori wahala oriṣiiriṣii yii loun ṣe pepade nla, pe ki gbogbo awọn pe lati jiroro lori eto ẹko giga nilẹ wa, ki ohun gbogbo le maa lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

Ṣugbọn awọn olukọ yunifasiti ko gba eyi wọle rara, ariwo ti won si n pa ni pe iwa ika, iwa alai-nikan-an-ṣe ni ijoba yii hu nipa fifi aabọ owo-oṣu ranṣẹ sawọn. Awọn olukọ naa ni awọn pada sẹnu iṣẹ pẹlu ero pe ijọba yoo mu awọn ẹjẹ ti wọn ṣe pẹlu awọn ṣẹ ni, ko sẹni to mọ pe wọn tan awọn lati da awọn pada sẹnu iṣẹ ni. Nidii eyi, ẹgbẹ ASUU ti n sare pepade, awọn ọga ileeṣẹ to n ri si eto-ẹkọ funjọba apapọ naa n ṣepade, Buhari si ni Gbajabiamila ni awọn n reti pẹlu oju aanu ẹ yii, bi ọrọ yii ko ṣe tun ni i dija, iyẹn wa lọwọ awọn alagbara o!

Leave a Reply