Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ijọba ipinlẹ Kwara ti mu ileri rẹ ṣẹ pẹlu fun awọn to padanu dukia wọn nibi ijamba ina to waye ninu ọja to gbajugbaja niluu Oro, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara, laipẹ yii, ni miliọnu mẹta naira gẹgẹ bii owo iranwọ.
Aafin ọba ilu Oro ni wọn ti gbe owo naa le wọn lọwọ. Akọwe ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ naa, Arabinrin Motunrayọ Adaran, lo gbe owo naa kalẹ lorukọ ijọba, to si rọ wọn pe ki wọn lo o gẹgẹ bo ti yẹ. O tẹsiwaju pe ijọba ko le san gbogbo owo ọja ti wọn padanu tan, wọn kan fi eyi ran wọn lọwọ ni. Ṣaaju ni gomina ti ṣabẹwo si ọja ọhun lati mọ bi nnkan ṣe bajẹ si, lasiko ti ina ọhun ṣọṣẹ.
Awọn to sọrọ lorukọ gbogbo awọn to jẹ anfaani owo naa, Babalọja ati Iyalọja ọja naa, Ọgbẹni Tijani Sodiq ati Arabinrin Mulikat Jimoh, dupẹ lọwọ Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, pẹlu gẹgẹ bo ṣe mu ileri rẹ ṣẹ, to si peṣe owo iranwọ fawọn ara ọja naa to fara kaasa ninu ijamba ina ọja Oro yii. Wọn ni gbọn-in gbọn-in lawọn wa lẹyin iṣejọba rẹ, wọn gbadura fun gomina pe Ọlọrun yoo maa tọ ọ sọna lati tukọ ipinlẹ Kwara de ebute ogo.