Ijọba Kwara fẹẹ ṣe iwosan ọfẹ fawọn ọmọde 

lbrahim Alagunmu, Ilorin

Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ isejọba Abdulrahman Abdulrasaq, ti sọ pe, awọn yoo peṣe iwoṣan ọfẹ fun awọn ọmọde to ni aarun iba ti kodin ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta (600, 000) nijọba ibilẹ mọkanla nipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si eto ilera nipinlẹ naa fi sita latọwọ akọwe wọn, Falade Gbenga Tayọ, o ni eto ṣiṣe iwoṣan arun iba fun awọn ọmọde yii ko sẹyin ilakaka Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, lati gbogun ti arun iba nipinlẹ Kwara.

Kọmisanna lẹka eto ilera nipinlẹ ọhun, Dokita Raji Rasaq, ti waa juwe igbesẹ gomina gẹgẹ bii ọna lati mu nnkan rọrun fawọn olugbe ipinlẹ Kwara paapaa awọn ti ko rọwọ họri. O tẹsiwaju pe, eto naa ni ijọba Kwara gbe kalẹ pẹlu ajọsepọ ajọ to n gbogun ti arun iba lagbaaye, lati ri i pe arun naa dohun igbagbe lara awọn ọmọde nipinlẹ yii ati awọn ipinlẹ miiran jake-jado ilẹ yii.

 

Gomina Abdulrahman ti waa ṣeleri pe oniruuru eto loun yoo gbe kalẹ lẹka eto ilera lati ri i pe eto ilera duro re nipinlẹ oun.

Leave a Reply