Ijọba mu awọn ọdaran ti wọn n sun oju irin reluwee, eyi lohun ti wọn ba lọwọ wọn

Monisọla Saka

Ọwọ ijọba ipinlẹ Eko ti tẹ awọn afurasi mẹrinlelaaadọrun-un, lasiko tileeṣẹ to n ri sọrọ ayika nipinlẹ naa, wọde laarin oru.

Awọn ti wọn n gbe laaye ti ko yẹ, janduku, atawọn afurasi ọdaran, ti wọn fi oju irin reluwee ṣebugbe, ni wọn lọọ fi panpẹ ọba gbe, lẹyin oniruuru ẹjọ tawọn araalu fi n sun.

Tokunbọ Wahab, ti i ṣe kọmiṣanna fọrọ ayika ati omi, lo kede ọrọ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Lara nnkan ti wọn ri gba lọwọ awọn afurasi ti wọn ko ọhun ni ibọn punpu, igbo atawọn oogun oloro mi-in ti wọn ti we kalẹ, oogun abẹnu gọngọ, ọbẹ aṣooro atawọn nnkan mi-in.

“Ni idahun si aroye awọn araalu, ero to n lọ to n bọ atawọn tọrọ naa ka lara lori awọn iwa ti ko bofin mu ti awọn janduku, afurasi ọdaran atawọn to sọ oju irin dile n hu lo mu ki ileeṣẹ yii wọde laarin oru lọ si oju irin to wa lagbegbe abẹ biriiji Pen-Cinema, si Fagba Junction.

“Laago meji aabọ oru ni a bẹrẹ si i wọde kiri, laarin kilomita marun-un ti a rin yii, gbogbo awọn ile kolobo kolobo ti wọn fi pako kọ atawọn aaye mi-in ti wọn fi ṣe ile ni a wo danu.

“Awọn afurasi mẹrinlelaaadọrun-un ni a fi panpẹ ọba gbe lasiko ti a wọde, pẹlu oriṣiriṣii oogun oloro, ibọn ilewọ ti wọn n rọ nilẹ yii, oogun, ọbẹ, ti a ka mọ wọn lọwọ”.

Tokunbọ ni awọn yoo foju gbogbo wọn bale ẹjọ laipẹ.

 

Leave a Reply