Ijọba Ọṣun fọwọ si yiyan awọn ọba tuntun mẹfa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Igbimọ alaṣẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede yiyan awọn ọba tuntun mọkanla.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ, Amofin Kọlapọ Alimi, fi sita lo ti ṣalaye pe ninu ipade igbimọ naa to waye laipẹ yii ni wọn ti gbe igbesẹ naa.

Alimi sọ pe loju ẹsẹ ni iyansipo naa yoo gbera sọ, bẹẹ lo si rọ awọn ori-ade tuntun naa lati ri i pe alaafia jọba lagbegbe wọn.

Awọn ọba tuntun naa ni Ọmọọba Haastrup Adeọla Ojo, to jẹ Aloro ti Iloro-Ijesha, ni Ila-Oorun Atakunmọsa.

Ọmọọba Mark Adeniyi Ajewọle, to jẹ Onisẹ of Isẹ-Ijeṣa, ti Ila Oorun Atakunmọsa. Ọmọọba Adekunle Waheed Babatunde, gẹgẹ bii Elende ti Eko Ende, nijọba ibilẹ ̣Ifẹlodun.

Awọn yooku ni Ọmọọba Sulaimon Adebayọ Ọlalekan, ti Olu Alajuẹ, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ẹdẹ, Ọmọọba Badmos Rafiu Ọmọtọṣọ, to jẹ Alagbeye ti Agbeye, nijọba ibilẹ Guusu Odo Ọtin ati Ọmọọba Johnson Oyewale Ajiboye, ti Ọlọ́là ti Ọlà, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ejigbo.

Alimi ke si awọn ilu ti wọn ṣẹṣẹ ni ọba naa lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ori-ade tuntun yii fun idagbasoke agbegbe wọn.

Leave a Reply