Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn afọbajẹ ilu Iree ti sọ pe awọn ko mọ si bi wọn ṣe yan Ọmọọba Raphel Ademọla gẹgẹ bii Aree ti ilu Iree, bẹẹ ni wọn naka aleebu si kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye-jijẹ, Ọnarebu Bayọ Adeleke, pe o fagbara yan ọba fun ilu naa.
Ọkan lara awọn afọbajẹ ilu yii, Aogun ti Iree, Oloye Saliu Atoyebi, ẹni to ba awọn oniroyin sọrọ lorukọ Aree-in-Council, ṣalaye pe wọn ko ti i yan ọba fun ilu Iree.
“Ohun to lẹtọọ ki wọn ṣe ni lati ko awọn ọmọọba ti wọn n du ipo naa lati idile mẹrẹẹrin wa sọdọ awa afọbajẹ lati ba Ifa sọrọ.
“Wọn ko ṣe gbogbo eleyii, ohun ti wọn ṣe loni-in yatọ si ilana yiyan Aree tuntun. Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ijọba mu iwe wa fun wa pe awọn fẹẹ yan Iyalode gẹgẹ bii ijoye alakanṣe iṣẹ, gbogbo wa la yari kanlẹ nitori obinrin ko le si laarin awa afọbajẹ.
“Lẹyin naa ni Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Bayọ Adelele, pe ipade si aafin, nibi to ti halẹ mọ gbogbo wa, to si leri pe oun n pada bọ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lati fi agidi mu wa ṣe iḟẹ inu ẹ, idi niyẹn ti gbogbo wa fi sa lọ”.
Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori awọn ẹsun naa, Ọnarebu Bayọ Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Banik, sọ pe nigba ti awọn afọbajẹ kuna ojuṣe wọn lo jẹ kijọba yan awọn ijoye alakanṣe iṣẹ niwọn igba to wa lakata agbara ijọba ti iru iṣẹlẹ bẹẹ ba ṣẹlẹ.
Adeleke sọ siwaju pe ẹẹmẹta ọtọọtọ ni wọn pe awọn afọbajẹ naa lati jokoo yan Aree tuntun, ṣugbọn ti wọn kọ jalẹ. O ni gbogbo ilana to yẹ lawọn tẹle lati yan ọba tuntun naa.
Lọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ni awọn ijoye alakanṣe iṣẹ (Warrant Chiefs) yan Ọmọọba Raphel Ademọla, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta gẹgẹ bii Aree ti ilu Iree tuntun.
Aree tuntun, ẹni to wa latile ọlọmọọba Ọyẹkun, niluu naa, lawọn ijoye ọhun yan labẹ iṣakoso awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ agbegbe idagbaspoke Ariwa Boripẹ, tibujoko rẹ wa niluu Iree.
Oṣu keje, ọdun 2018, ni ipo Aree ti ilu Iree ṣi silẹ lẹyin ti Ọba Jimọh Ọlayọnu to jẹ Aree kẹẹẹdogun darapọ mọ awọn baba nla rẹ.