Ijọba ti ṣọọṣi Ridiimu atawọn ile itaja igbalode kan pa l’Ekoo, eyi lohun to fa a

Adeoye adewale

Afi bii ala lọrọ ọhun jọ loju awọn araalu kan, paapaa ju lọ awọn ọmọ ijo ṣọọṣi The Redeemed Christian Church of God kan, nigba tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba kan to n ri sọrọ ayika nipinlẹ Eko, ‘Lagos State Environmental Protection Agency’ (LASEPA), bẹrẹ si i fi kọkọrọ ti awọn ilẹkun to wọnu ṣọọṣi naa pa. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n fi ariwo tiwọn di araalu yooku lọwọ ni gbogbo igba. Yatọ sileejọsin ọhun ti wọn ṣa ni kọkọrọ pa, wọn tun ti awọn otẹẹli ati ileeṣẹ kan ti wọn ti n tẹwe  pa patapata, nitori ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn ko bọwọ fun ofin ayika nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe awọn agbegbe tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba naa ti lọọ ṣiṣẹ ni awọn aduugbo bii: Ikeja, Mushin, Gbagada ati Maryland.

Alakooso ileeṣẹ LASEPA nipinlẹ Eko, Dọkita Babatunde Ajayi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹan-an, ọdun yii, sọ pe awọn gbe igbesẹ naa ni ibamu pẹlu ilana ati ofin to rọ mọ ilu Eko ni. O ni ariwo buruku lawọn ileeṣẹ atawọn ile ijọsin tawọn ti pa naa fi n daamu awọn olugbe agbegbe yii, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ rara.

Lara awọn ile ijọsin atawọn ile itaja igbalode ti wọn ti pa ni: Vital Products Limited, A& P Nigeria Ltd, Polite Anchorage and Suite, The Redeemed Christian Church of God, Terrag Inn Apartment. Evening Class Guest House, Celestial Church of God, Charley’s Bar ati 7th Heaven Hotel and Suite.

Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘Kaakiri aarin ilu Eko lawọn oṣiṣẹ ajọ LASEPA lọ, wọn lọọ fọwọ ofin mu awọn ti wọn joye aletilapa, ti wọn ko bọwọ fun ofin ayika nipinlẹ Eko. Gbogbo awọn ti wọn tapa sofin ayika nipinlẹ Eko la ti da sẹria fun, a ti awọn ileeṣẹ wọn pa, bakan naa lawọn ṣọọṣi kọọkan naa n fi ariwo tiwọn di araalu lọwọ. Idi pataki ta a ṣe n ṣe eyi ni pe, ofin wa l’Ekoo, ko sẹni to gbọdọ fọwọ pa ida ofin ijọba Eko loju.

 

Leave a Reply