Adewale Adeoye
Awọn agba bọ wọn ni ilu ti ko ba ti sofin, ko si ẹṣẹ nibẹ, ṣugbọn ijiya nla lo wa fun araalu to ba tapa sofin biluu ba lofin. Eyi lo mu ki ijọba ipinlẹ Eko ti awọn ileejọsin kan pa l’Ekoo, nitori ti wọn tapa sofin ayika nipinlẹ naa.
ALAROYE gbọ pe kaakiri awọn agbegbe bii: Ikẹja, Ọgba, Surulere, Sabo Yaba, Ebute-Mẹta, ati Ṣomolu, nipinlẹ Eko, lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba ipinle Eko to n ri sọrọ ayika ‘Lagos State Environmental Protection Agency’ (LASEPA) ti lọọ fọwọ ofin mu awọn araalu ti wọn ba tapa sofin ayika nipinlẹ naa.
Lara awọn ibi ti awọn oṣiṣẹ ajọ naa ti pa nitori ti wọn n fi ariwo tiwọn di araalu lọwọ ni mọṣalaṣi kan bayii wa.
Ọga agba ajọ LASEPA, Dokita Babatunde Ajayi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe, ‘‘Kaakiri aarin ilu Eko lawọn oṣiṣẹ ajọ LASEPA lọ lati lọọ fọwọ ofin mu awọn ọbayejẹ ẹda gbogbo ti wọn ko bọwọ fun ofin ayika nipinlẹ Eko. Lara ibi ta a lọ ni Ikeja, Ọgba, Surulere, Sabo Yaba, Ebute-Mẹta ati Ṣomolu. A ti awọn ile ijọsin atawọn ile itaja igbalode kan pa.
‘’A ti ile ounjẹ igbalode kan ti wọn n pe ni 12 Meals Lounge, Bel Papyrus, Grand Hyatt, Oluwatoyin Mosque, Multistyle Supermarket, Special Bread Bakery ati Understanding Bar. Gbogbo wọn pata ni wọn jẹbi awọn ẹsun ta a fi kan wọn, bẹẹ ki i ṣe igba akọkọ ree ta a maa ki wọn nilọ, wọn ko tẹle aṣẹ ati ofin ayika nipinlẹ Eko la ṣe ti wọn pa bayii.
O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn to ba tapa sofin ayika nipinlẹ Eko. Fun idi eyi, o rọ awọn oniṣowo atawọn araalu pe ki wọn ma ṣe fọwọ pa ida ijọba loju, ko ma baa ge wọn lọwọ.