Adewale Adeoye
Awọn alaṣẹ ijọba apapọ orile-ede Naijiria ti fẹẹ fontẹ lu u pe ki awọn ẹṣọ aṣọbode ilẹ wa ṣi bọda Sẹmẹ, kawọn oniṣowo ti wọn n ta mọto le lanfaani lati maa ko mọto tokunbọ wọle lọpọ yanturu gẹgẹ bo ti ṣe wa tẹlẹ.
Ọgbẹni Ibrahim Musa to jẹ ọkan pataki lara ọga agba ni ẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ ohun irinna lorileede yii lo sọrọ ọhun di mimọ nibi ipade awọn orileede ti wọn jọ n ṣe ajọṣepọ lori ọrọ-aje ti wọn pe ni ‘Economic Community Of West Africa State’ (ECOWAS) eyi to waye laarin awọn aṣoju orile-ede Naijiria ati tilẹ Benin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii. Nibi ipade ọhun ni Ibrahim ti sọ pe, awọn alaṣẹ ijọba orileede Naijiria ti gbọ igbe ati ẹbẹ awọn oniṣowo gbogbo ti wọn n ko mọto tokunbọ wọlu, ti wọn si ti fẹẹ fontẹ lu u pe, ki wọn maa ko awọn mọto ọhun wọle, bo ti ṣe wa tẹlẹ.
Ibrahim ni, ‘’Mo ranti daadaa pe emi pẹlu minisita fun ohun irinna lorile-ede Naijiria tẹlẹ la jọ wa sibi lasiko naa, tawọn oniṣowo mọto tokunbọ si bẹbẹ pe ka jẹ kawọn maa kọ awọn mọto tokunbọ naa wọle, minisita si ṣeleri nigba naa pe oun yoo sa gbogbo ipa oun lori ọrọ naa. O gbiyanju lati ba awọn alakooso ijọba akoko naa sọrọ, wọn si ti gba si i lẹnu bayii, orile-ede Naijiria ti fẹẹ gbẹsẹ kuro lori bi wọn ṣe ti bọda Sẹmẹ pa patapata tẹlẹ. A ti fẹẹ ṣi bọda Sẹmẹ bayii fun lilo awọn to n ṣowo mọto tokunbọ bayii’’.
Lori igbesẹ tawọn alaṣẹ ijọba orileedeNaijiria gbe yii, ọkan lara awọn ọga agba aṣọbode lorileede Benin, Ọgbẹni Dera Nnadi, ti dupẹ gidi lọwọ awọn alaṣẹ ijọba ilẹ wa, o sọ ipalara nla ti bọda Sẹmẹ ti wọn ti pa ọhun ṣe fun ọrọ aje orile-ede wọn latọjọ tawọn alaṣẹ Naijiria ti gbe igbesẹ ti wọn gbe naa.
O ni iye owo to n wọle sapo ijọba awọn ti dinku gidi, gbogbo nnkan ko si lọ deede mọ fawọn ọmọ orileede naa. O ni bi wọn ti ṣe fẹẹ ṣi bọda naa bayii yoo mu ki nnkan pada bọ sipo fawọn laipẹ rara.