Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina Rotimi Akeredolu ti gbẹsẹ kuro lori ofin konilegbele oniwakati mẹrinlelogun tijọba kede rẹ latari rogbodiyan to suyọ lori iwọde SARS ti wọn ṣe lawọn apa ibi kan nipinlẹ Ondo.
Ikede yii waye ninu atẹjade ti gomina fi sita lati ọwọ Kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Akeredolu ni oun pinnu lati fagi le ofin konilegbele naa latari iroyin ti oun gbọ lati ẹnu awọn ẹsọ alaabo ipinlẹ Ondo pe alaafia ti n jọba niluu Akurẹ ati awọn agbegbe mi-in ti wọn ti fa wahala lasiko iwọde SARS.
O fi kun un pe awọn ẹsọ alaabo wọnyi si n tẹsiwaju ninu pipeṣe aabo fawọn eeyan lawọn apa ibi kan nipinlẹ Ondo.
Gomina waa rọ awọn araalu lati gba alaafia laaye, ki wọn si yago fun ohunkohun to ba lodi sofin.