Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Laarin wakati diẹ tawọn ile-ẹkọ di ṣiṣi pada nipinlẹ Ondo, ijọba ti pasẹ pe ki wọn ti ile-iwe girama meji pa lori ẹsun ṣiṣe lodi sofin ati ilana arun Korona.
Awọn ile-iwe mejeeji tọrọ kan ni ileewe girama CAC to wa loju ọna Akurẹ si Ondo, ati Akurẹ Academy, to wa l’Ọba-Ile.
Akọwe agba fun ileesẹ to n ri seto ẹkọ nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Akin Asaniyan to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni ohun to ṣokunfa igbesẹ yii ko sẹyin bawọn olori ileewe mejeeji ṣe kuna lati tẹle gbogbo alakalẹ tijọba fun wọn.
Awọn akẹkọọ ileewe wọnyi lo ni awọn ri ti wọn n rin kiri igboro lasiko to yẹ ki wọn wa ninu kilaasi wọn nigba ti wọn da awọn mi-in sita lati maa ge koriko to wa ninu ọgba ati ayika ileewe.
Ọgbẹni Asaniyan ni ijọba ko ni i fojuure wo ileewe to ba ru eyikeyii ninu ofin ati ilana tijọba fi lelẹ lori ajakalẹ arun Korona to n ṣoro bii agbọn lọwọ.