Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Pẹlu bi ajakalẹ arun Korona ṣe ti dinku daadaa nipinlẹ Ogun, Gomina Dapọ Abiọdun ti paṣẹ pe kawọn ileejọsin (ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi) pẹlu ileewe atawọn otẹẹli nipinlẹ yii bẹrẹ si i ṣilẹkun wọn pada bíi tatijọ.
Yatọ sawọn yii, awọn ile sinima, gbọngan ayẹyẹ, ile ounjẹ igbalode, ibi igbafẹ ati ibudo abẹwo awọn alejo pelu awọn ọja naa ti lanfaani lati bẹrẹ iṣẹ wọn ni kikun pada, bi wọn ṣe n ṣe e ki Korona too de.
Ọjọruu ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ni gomina sọ eyi di mimọ ninu atẹjade ti Akọwe iroyin ẹ, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, fi sita lalẹ Wẹsidee.
Atẹjade yii waa la awọn ofin to rọ mọ ṣiṣi naa kalẹ, paapaa fawọn onile ounjẹ igbalode atawọn onigbọngan ayẹyẹ.
Awọn ti yoo ba wọle sọdọ wọn gbọdọ lo ibomu, wọn gbọdọ takete sira wọn niwọn ẹsẹ bata meji. Wọn gbọdọ fi ẹrọ ayẹwo to n yẹ ara ẹni wo yẹ wọn wo ki wọn too wọle, awọn onile faaji naa si gbọdọ fa ila tawọn onibaara wọn yoo fi mọ bo ṣe yẹ ki wọn ta kete sira wọn to.
To ba jẹ ile ounjẹ igbalode ni, eeyan ko gbọdọ ju mẹrin lọ lori tabili kan, ko si saaye a n bu ounjẹ funra ẹni (Buffet)
Ki ayẹyẹ eyikeyii too waye rara ni gbọngan ayẹyẹ, awọn to fẹẹ ṣe e gbọdọ gbawe aṣẹ latọdọ ìjọba.
Ida aadọta (50) ni ààye tijọba ipinlẹ Ogun gba pe kawọn onibudo itaja fun onibaara, ko gbọdọ si a n pariwo di ará yooku lọwọ lawọn ile igbafẹ ati ibi fàájì, awọn ile sinima ko si gbọdọ kọja aago mẹwaa lalẹ ti wọn yoo fi tilẹkun wọn.
Bi ẹnikẹni tabi ileeṣẹ ba waa tapa sawọn ofin yii, ijọba ni ijiya to nipọn wa. Yatọ si pe tọhun yoo sanwo itanran, wọn yoo tun ti ileeṣẹ rẹ naa pa.
Wọn fi kun un pe awọn oṣiṣẹ amunifọba ti wa kaakiri láti mu awọn to ba tapa sofin wọnyi, ijọba loun ko fẹ ki Korona tun gbalẹ lẹyin anfaani yii, ìyẹn lo jẹ ki wọn fi awọn ofin to le mu ero rere ijọba yii ṣẹ kun un.