Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nitori apọju idọti ati ẹgbin oriṣiiriṣii to wa ninu ọja Ibẹrẹkodo, l’Abẹokuta, ijọba ipinlẹ Ogun ti ti ọja naa bayii, ko ma baa di ohun ti yoo fa ajakalẹ arun ti apa ko ni i ka, paapaa arun onigbameji ti wọn n pe ni Kọlẹra (Cholera).
Nigba to n kede bi wọn ṣe le awọn ara ọja naa kuro, ti wọn si ti i l’Ọjọruu, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, Oludamọran pataki fun Gomina Dapọ Abiọdun lori ọrọ ayika, Ọgbẹni Ọla Ọrẹsanya, ṣalaye pe ijọba gbe igbesẹ yii nitori òketè ilẹ ti wọn n da sibi kan ninu ọja Ibẹrẹkodo, eyi to ti ga bii oke, ti wọn ko si yee ṣe ẹgbin sibẹ.
O fi kun un pe yatọ si ti erekiti yii (bi wọn ṣe maa n pe e l’Abẹokuta), ayika ọja yii ko mọ rara, ẹgbin afojuri pọ ju. Bẹẹ, nnkan jijẹ bii eso atawọn ounjẹ mi-in pọ nibẹ ti wọn n ta, ẹgbin si le wọ ọ, ko di wahala fawọn to ba fowo wọn ra a atawọn ọlọja gan-an to n ta a funra wọn.
Idi eyi lo fi ni ko sohun to kan ju ki ọja yii wa ni titi pa titi digba ti wọn yoo fi ṣe atunṣe rẹ, ti ẹgbin buruku naa yoo ti kuro nibẹ patapata.
Ọrẹsanya to tun jẹ ọga to n ri si kolẹ-kodọti nipinlẹ Ogun, tẹsiwaju pe ijọba ko deede waa ti ọja Ibẹrẹkodo pa, o ni ọpọlọpọ igba nijọba ti kilọ fun wọn lati tun ayika wọn ṣe, ṣugbọn ti wọn ko dahun. Aidahun naa lo ni o fa a tawọn fi waa ti ọja, awọn ko si ni i ṣi i, afi tawọn ara ọja ba tun un ṣe funra wọn to ṣee ri, to si daa fun alaafia araalu.
O fi kun un pe ki i ṣe ọja Ibẹrẹkodo nikan lọrọ yii kan o, Ọrẹsanya kilọ fawọn ọja ojoojumọ yooku pẹlu awọn ọja ọlọjọ marun-un-marun-un to wa nitosi, o ni ki wọn kọgbọn lara Ibẹrẹkodo, ọja ti ayika rẹ tabi inu ẹ gan-an ba le ṣakoba fun ilera eeyan yoo di titipa ni.
Iyalọja Ibẹrẹkodo, Alaaja Mọnsurat Ọladipupọ, ti figba kan ba ALAROYE sọrọ lori okete ẹgbin to wa lọja yii, iyẹn lọdun 2019 ta a ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun un.
Mama naa sọ pe bi ọja Ibẹrẹkodo ṣe ti pẹ to ni erekiti to ga bii oke to wa nibẹ naa ṣe ti pẹ, bii nnkan agbọnjuba ti apa awọn ko ka ni.
O fi kun un alaye ẹ nigba naa pe ko si ileegbọnsẹ lọja yii, bẹẹ ni ko dẹrun lati tura rara, apa awọn ko si ka a lati da a ṣe, iranlọwọ ijọba lawọn n beere lati le sọ ọja iṣẹmbaye naa di tuntun bii tasiko yii.
Ṣugbọn nigba ti wọn ti i yii, Iyalọja ni gbogbo ipa lawọn yoo sa lati ri i pe ọja Ibẹrẹkodo mọ pada, awọn yoo ri si bii ẹgbin naa yoo ṣe lọ patapata, kawọn le bẹrẹ karakata pada lai si iyọnu.