Adewale adeoye
Ni bayii, titi pa patapata ni nijọba ipinlẹ Eko ti ileetaja igbalode kan ti wọn n pe ni ‘Blessed Happy Homes supermarket’ to wa ni 6th Avenue, ni Festac, nipinlẹ Eko pa. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n ta awọn ọja ti ọjọ ti lọ lori wọn fawọn araalu ti wọn ko mọ nnkan kan, eyi ti wọn sọ pe o lewu fun ilera wọn.
ALAROYE gbọ pe ẹka ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n ri sọrọ ayika ‘Lagos State Environmental and Water Resources’ ni wọn lọọ ti ileetaja naa pa.
Kọmiṣana fọrọ ayika nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tokunbọ Wahab, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun yii, sọ pe awọn araalu kan ti wọn mọ nipa ohun to lodi sofin tawọn eeyan naa n ṣe ni wọn waa fọrọ ọhun to awọn, leti tawọn si lọọ fọwọ ofin mu wọn.
Nigba to n ṣalaye b’ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi sita lo ti sọ pe, ‘’Ko si ani-ani kankan nibẹ, a maa ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ta a si maa foju awọn afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ laipẹ yii, ki wọn le jiya ẹṣẹ ti wọn ṣẹ. Ọja to ti bajẹ ni wọn ko jọ sinu ileetaja igbalode wọn lagbegbe 6th Avenue, ni Festac, ti wọn si n ta a fawọn onibaara wọn gbogbo ti wọn ko mọ pe awọn ọja naa ti bajẹ. Ohun aburu gbaa ni nnkan ti wọn n ṣe yii, ọja naa le pada ṣakoba nla fun ilera awọn araalu to ba jẹ ẹ. Ofin ko faaye gba a pe kawọn oniṣowo maa tawọn ọja to ba ti bajẹ, tabi tọjọ ba ti lọ lori rẹ sita, paapaa ju lọ nipinlẹ Eko, a ko ni i gba iru rẹ lae.’ Bẹẹ ni Wahab sọ.