Dada Ajikanje
Refurẹndi Ejike Mbaka, ti ileejọsin Adoration Ministries, niluu Enugu, ti ke sí Ààrẹ Muhammadu Buhari pe ko yẹra fún awọn ipinnu ijọba to le ko inira ba awọn ọdọ ti ko ba fẹ ki ijọba rẹ doju de laipẹ ọjọ. Lasiko to ṣètò ìsìn aṣewọnu-ọdun tuntun lo sọrọ yii.
Mbaka sọ pe ninu iran ti Ọlọrun fi hàn oun, awọn ọdọ Naijiria yóò tún jade lẹẹkan si i, ti ìjọba Buhari ko ba ṣètò to yẹ fún ìdàgbàsókè àti ohun tó le mú ìlọsíwájú bá wọn.
O fi kun un pé, ti Buhari ko ba ṣọra, o ṣee ṣe kí ìjọba ẹ ṣubu lojiji, ti ko ba mu ọrọ awọn ọdọ ni pataki.
Mbaka sọ pe asiko niyi fún Ààrẹ Naijiria lati ṣọra dáadáa, nitori Ọlọrun ti sọ pe ibinu oun n bọ lori awọn oloṣelu ti wọn ti da nnkan ru fun awọn ọmọ Naijiria.
O fi kun un pe ọna kan pataki fún ìjọba Buhari lásìkò yii ni lati ṣe awọn eto ti yóò fún àwọn ọdọ lanfaani ninu ijọba ẹ, dipo ṣiṣe eto to le ni wọn lara.
Ipese iṣẹ ti yóò ṣe wọn lanfaani naa wa lara ohun ti òjíṣẹ Ọlọrun yii beere fún fawọn ọdọ, ti ijọba Buhari bẹ fẹẹ ṣaṣeyọri ni Naijiria.
O ni asiko n bọ ti awọn ọdọ yóò dìde sí ijọba yii ti ko ba sì ètò rere tó lè ṣe wọn lanfaani, ati pe yóò sòrò fún ìjọba Buhari lati kapa wahala ọhun, bẹẹ lo ṣee ṣe ko da oju ijọba ẹ dé nígbà tí wahala ọhun ba fẹju gan-an.