Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Latari bi aṣa didabẹ fun obinrin ko ṣe ti i di ohun igbagbe rara nipinlẹ Ekiti, ajọ Hacey Health Initiative ti bẹrẹ ipolongo ati ikilọ kaakiri fawọn to ba ṣi n hu iwa naa.
Eyi waye lẹyin ọsẹ kan ti Erelu Bisi Fayẹmi ṣeto kan lori didabẹ fun obinrin, nibi ti oriṣiiriṣii awọn ti wọn ti dabẹ fun ni kekere atawọn to n ṣiṣẹ naa tẹlẹ ti sọ awọn ewu to wa nibẹ fun araalu.
Hacey to gbe eto naa kalẹ pẹlu owo iranwọ ajọ iṣọkan agbaye, United Nations Trust Fund, ni wọn gba awọn oniroyin niyanju lati polongo lori iwa ọdaran naa nibi eto kan ti wọn pe ni ‘Stop Cut’ (Ma ṣe dabẹ) nitori bi aṣa naa ṣe pọ lawujọ di asiko yii.
Akọsilẹ fi han pe ipinlẹ Ekiti, Oṣun ati Ọyọ ni aṣa naa ti wọpọ si ju nilẹ Yoruba, ati pe ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti lo ti pọ ju l’Ekiti.
Ninu ọrọ oṣiṣẹ ileeṣẹ eto ilera (Ministry of Health) Ekiti kan, Abilekọ Oluwakẹmi Akinlẹyẹ, o ni idi ti wọn fi bẹrẹ aṣa buruku yii ni nitori igbagbọ pe obinrin ti ko ba ṣe e yoo ya oniṣekuṣe, tabi pe ti wọn ko ba ge awọn ẹya kan loju-ara obinrin, ọmọ to ba bi yoo ku.
Akinlẹyẹ ṣalaye siwaju pe irora ti ko ṣee fẹnu sọ lawọn ti wọn ba da abẹ fun n la kọja, bẹẹ ni wọn tiẹ maa n ran oju-ara ẹlomi-in pa. Bakan naa ni wọn maa n lo abẹrẹ tabi irin gbigbona lati ṣiṣẹ abẹ naa, eyi ti yoo jẹ ki ẹjẹ sa kuro nibẹ.
O waa ni oriṣiiriṣii wahala ni eyi maa n fa fun obinrin, ko si si ere kankan ti aṣa naa n fun ẹni ti wọn ba ṣe e fun.
Bakan naa ni Amofin Blessing Ajilẹyẹ to ṣoju Amofin Rita Ilevbare sọ pe atunṣe ti ba ofin to ta ko iwa didabẹ fun obinrin nitori owo itanran ẹgbẹrun mẹwaa ati ẹwọn ọdun meji si mẹta lo wa gẹgẹ bii ijiya tẹlẹ, ṣugbọn o ti di ẹgbẹrun lọna igba ( 200,000) bayii.
Abilekọ Fatima Bello to jẹ alaga ẹgbẹ awọn oniroyin obinrin, ṣugbọn ti Ọgbẹni Caleb Obiṣẹsan ṣoju fun, sọ pe iṣẹ gbogbo eeyan ni ipolongo yii, gbogbo eeyan lo si gbọdọ mọ pe ibanujẹ ayeraye ni aṣa naa n mu ba awọn obinrin.
Ajọ Hacey ti waa bẹrẹ ipolongo lati sọ fun awọn eeyan pe ko si aaye tabi awawi fun aṣa yii mọ, ẹni tọwọ ba si ba yoo da ara ẹ lẹbi.