Ikọja aaye, Ibrahim fọwọ fa ọyan iyaale ile kan, ladajọ ba ju u sẹwọn

Monisọla Saka

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Badagry, nipinlẹ Eko, ti paṣẹ pe ki wọn ju ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji (41) kan, Ibrahim Lemo, sẹwọn, nitori ọyan obinrin olobinrin, Zainab Babalọla, to fa. Ki i ṣe pe o fa ọyan obinrin yii nikan, wọn lo tun lu obinrin to huwa idọti si yii, lẹyin tiyẹn sọ fun un pe ko jawọ ninu palapala to n ba oun ṣe.

Iwaju Onidaajọ Fadahunsi Adefioye, ti ile-ẹjọ Majisireeti kan ni wọn wọ Ibrahim to sọ ọyan obinrin olobinrin di rọba, to si n fa a yii lọ.

Aṣoju ijọba ni kootu ọhun, ASP Clement Okuoimose, ṣalaye fun ile-ẹjọ pe ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni olujẹjọ ṣẹ ẹṣẹ ti wọn pe e lẹjọ fun yii, nile itaja igbalode to wa lorita olobiiripo (roundabout), Badagry, nipinlẹ Eko.

Clement ni lai jẹ pe o gbaaye lọwọ obinrin naa, tabi pe wọn jọ ni ajọsọ ọrọ tẹlẹ, Ibrahim fọwọ tẹ ọyan Zainab, ti i ṣe olupẹjọ. Bakan naa lo tun sọ pe ọkunrin yii tun gba ọmọbinrin naa loju, nibi ẹyinju rẹ lapa osi, nigba ti tọhun sọ fun un pe ko ma fọwọ kan oun mọ.

Agbefọba ni iwa t’ọkunrin yii hu ta ko abala kẹrinlelaaadoje ati aadọjọ, iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko, ti ọdun 2015.

Ninu ọrọ rẹ, Ibrahim jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun meji to ni i ṣe pẹlu ka maa rẹ ni jẹ, ka si maa fọwọ agbara mu ni, ti wọn ka si i lọrun.

Eyi lo mu ki adajo paṣẹ pe ki wọn maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn Awhajigoh, to wa niluu Badagry, nipinlẹ Eko. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, fun awọn ẹri loriṣiiriṣii ati idajọ.

Leave a Reply