Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbẹjọ to yẹ ko tẹ siwaju lonii ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun 2022, lori ẹsun ti wọn fi kan Dokita Rahmon Adedoyin to ni ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa, ni ko le waye latari bi wọn ko ṣe ri ẹlẹrii ti Adedoyin sọ pe oun fẹẹ pe mu wa si kootu.
Adedoyin, Adedeji Adeṣọla, Magdalene Chiefuna, Adeniyi Aderọgba, Oluwọle Lawrence, Oyetunde Kazeem, ati Adebayọ Kunle ni wọn ti bẹrẹ ijẹjọọ latibẹrẹ ọdun yii lori iku to pa akẹkọọ Fasiti Ifẹ kan, Timothy Adegoke, si otẹẹli wọn loṣu Kọkanla, ọdun 2021.
Ninu igbẹjọ to kọja, Adajọ agba nipinlẹ Ọṣun to n gbọ ẹsun naa, Bọla Adepele-Ojo, dajọ pe agbẹjọro olupẹjọ, Fẹmi Falana, SAN, lẹtọọ labẹ ofin lati fi kun ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ.
Nigba naa ni agbẹjọro Adedoyin, K. Ẹlẹja, sọ pe onibaara oun yoo pe ẹlẹrii kan, bẹẹ ni awọn agbẹjọro fun awọn olujẹjọ to ku naa sọ iye awọn ẹlẹrii ti awọn yoo pe, ti wọn si sun igbẹjọ siwaju di Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila.
Lẹyin ti akọwe kootu ṣafihan awọn olujẹjọ mejeeje ni Barisita Ẹlẹja, SAN, dide sọ fun kootu pe ẹlẹrii ti Adedoyin fẹẹ lo ko lanfaani lati fara han ni kootu nitori iṣẹ ti gbe e kuro nitosi.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ọlọpaa ni ẹlẹrii naa, ojiji si ni iṣinipo rẹ de, idi niyẹn ti ko fi lanfaani lati wa si kootu fun ijẹrii.
Ni ti awọn olujẹjọ keji, ikẹrin ati ikarun-un, agbẹjọro wọn, Muritala Abdulrosheed, SAN, sọ pe awọn ẹlẹrii toun ti ṣetan ṣugbọn o pe akiyesi kootu si bi agbẹjọro olupẹjọ, Fẹmi Falana, SAN, ko ṣe wa si kootu.
O beere lọwọ kootu boya Agbẹjọro Fatima Adeṣina to n ṣoju fun Falana lagbara lati beere ibeere (cross examine) lọwọ ẹlẹrii ti oun fẹẹ pe.
Lasiko yii ni Agbẹjọro Adeṣina dide, o ni aṣẹ ti Falana gba lati ṣẹjọ naa wa fun ọfiisi (Chamber) rẹ, nitori naa, ẹnikẹni ti ọfiisi naa ba ran wa lanfaani lati ṣiṣẹ lorukọ Falana.
Nigba to n sọrọ lori ẹ, Onidaajọ Adepele Ojo sọ pe yatọ si ariyanjiyan lori pe boya agbẹjọro kan le ṣoju Falana, niwọn igba ti ẹlẹrii akọkọ ko ti fara han ni kootu, ko boju mu lati tẹsiwaju ninu igbẹjọ naa.
Nitori naa, o sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹẹdogun oṣu kejila, ọdun yii.