Monisọla Saka
Alaaji Atiku Abubakar, to tun jẹ oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, lasiko ibo ọdun to kọja, ti ni niwọnba igba toun ba ṣi wa laye, ti alaafia oun ṣi pe perepere, oun ko ni i yee dupo aarẹ Naijiria titi toun yoo fi debẹ.
Lori eto kan ti wọn n ṣe lede Hausa lori tẹlifiṣan Voice of America, niluu Abuja, ni ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin naa ti sọrọ yii di mimọ.
Atiku to ti n lulẹ ninu awọn eto idibo bii mẹfa to ti n dupo aarẹ lati ọjọ yii wa sọ pe itan oṣelu Aarẹ Abraham Lincoln ti ilẹ Amẹrika ti ko moke nigba akọkọ to dupo aarẹ lo n fun oun nireti pe oun ṣi le wọle.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin yii yoo pe ọdun mọkanlelọgọrin lọdun 2027 ti wọn yoo ṣeto idibo mi-in lorilẹ-ede yii, Atiku fesi nigba ti wọn bi i pe ṣe o ti rẹ ija rẹ bayii, abi yoo tun dupo si i pe, “Bẹẹ ni, niwọn igba ti n ba wa laye ati lalaafia ara, ma a maa dupo aarẹ lọ ni.
Ẹyin ẹ wo aarẹ igba kan nilẹ Amẹrika, Abraham Lincoln, ẹẹmeje lo gbegba ibo ko too pada wọle.
“Amọ ta a ba wo bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe wa nisinyii, o han daju pe iṣẹ ẹgbẹ wa nikan ko to lati jawe olubori ninu ibo to n bọ. Atilẹyin to duroore ati didapọ mọ ẹgbẹ mi-in ṣe pataki”.
Nigba to n sọrọ nipa rogbodiyan to n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu wọn, o ni ifọwọsowọpọ ati idapọ pẹlu ẹgbẹ mi-in yoo mu ki ati wọle sipo aarẹ ẹgbẹ awọn rọrun lọdun 2027.
Ọrọ ti Atiku sọ yii lo lodi si nnkan to sọ lasiko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ BBC Hausa lọsẹ to lọ lẹyin to ṣepade bonkẹlẹ pẹlu Peter Obi atawọn oloṣelu jankanjankan kan. Ohun to wi ni pe ti ẹgbẹ awọn ba da pọ mọ Labour Party, ti wọn gbe ipo aarẹ lọ si apa Guusu orileede yii, ti wọn si fa Peter Obi kalẹ, gbogbo ara loun yoo fi ṣatilẹyin fun un.
Ṣugbọn pẹlu ohun ti ọkunrin ara Adamawa yii tun sọ yii, o da bii pe ọrọ rẹ ko ti i ṣee gbagbọ, nitori ko jọ pe o ti i mọ odo ti yoo da ọrunla rẹ si.