Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Latari iku to pa ọmọ ọkan lara awọn mọlẹbi gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, David Adeleke, ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ti kede pe ki gbogbo eto oṣelu duro niyooku ọsẹ yii lati ṣọfọ ọmọdekunrin naa, Ifeanyi.
Adele alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọṣun, Dokita Adekunle Akindele, ninu atẹjade kan to fi sita lo ti paṣẹ pe ki gbogbo ẹka ati oniruuru igbimọ ẹgbẹ naa ma ṣe ṣe ohunkohun lasiko yii lati fi ba idile Adeleke kẹdun iṣẹlẹ ajalu nla naa.
Adekunle ni, “A ṣọfọ iku ọmọ wa, Ifeanyi. A gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere. Ohun ibanujẹ nla ni, ṣugbọn igbagbọ wa ko yẹsẹ ninu Ọlọrun to da aye.
“A kẹdun pẹlu Davido, aṣoju awọn ọdọ wa. A kẹdun pẹlu baba wa, Dokita Deji Adeleke, ati gbogbo idile Adeleke. A gbadura pe ki Ọlọrun fun wọn ni okun lati gba ajalu nla yii”.