Iku oro o! Wọn tẹ aadọsan-an awọn to n woran bọọlu pa

Faith Adebọla

O kere tan, ọrinlelaaadọsan-an lara awọn to dagbere nile nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ ki-in-ni, oṣu Kẹwaa yii, p’awọn fẹẹ lọ woran bọọlu ni papa iṣere Malanga, lorileede Indonesia, ni wọn ko pada sile laaye mọ, niṣe lawọn ero tẹ wọn pa nigba ti akọlukọgba waye lopin ere idaraya naa. Nnkan bii ọgọsan-an mi-in lo ṣi wa lọsibitu, tori wọn fara ṣeṣe gidi.

Ilu Malanga, ni Ila-Oorun Java, lorileede Indonesia niṣẹlẹ ibanujẹ naa ti waye, wọn ni iṣẹlẹ yii lo ti i buru ju lọ latigba tawọn eeyan ti n ku ni papa iṣere lagbaaye, tori eyi nigba akọkọ tẹmii eeyan to pọ to bẹẹ yoo sọnu labẹ atẹlẹsẹ awọn onworan.

Ifẹsẹwọnsẹ ọjọ naa waye laarin ẹgbẹ agbabọọlu Arema ti alatako wọn, Persebaya Surabaya, ṣugbọn Arema lo gba Pasebaya lalejo, ọdọ wọn ni papa iṣere naa wa.

Ba a ṣe gbọ, ere ọjọ naa ro toto, latigba ti awọn mejeeje ti gba ami-ayo meji meji wọle ara wọn lawọn ololufẹ wọn ti n reti ohun ti yoo ṣẹlẹ, ṣugbọn lai ro ti ni Pasebaya gba bọọlu sawọn Arema, ko si ju iṣẹju diẹ ti ifẹsẹwọnsẹ naa pari lọ.

Wọn ni nina ti ẹgbẹ agbabọọlu Pasebaya Surabaya waa na Arema mọle yii lo bi awọn ololufẹ wọn ninu, ni wọn ba fija pẹẹta pẹlu awọn alejo wọn, ija naa si bẹrẹ si i ran bii ina ọyẹ.

Kia lawọn ọlọpaa to wa nitosi ti bẹrẹ si i yin afẹfẹ taju-taju saarin awọn arijagba yii, eyi lo si mu ki ọrọ di akọlukọgba, bawọn eeyan ṣe n sa fun afẹfẹ oro naa, wọn ko riran daadaa, ọpọ ko si le mi daadaa, bi awọn kan ṣe n ṣubu, bẹẹ lawọn to n sare jade, ti wọn o fẹẹ fara kaaṣa eemi buruku naa, bẹrẹ si i tẹ wọn mọlẹ lọ, titi ti wọn fi tẹ wọn pa.

Ọga ọlọpaa Ila-Oorun Java, Ọgbẹni Nico Afinta, lasiko to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan sọ pe awọn ọlọpaa meji wa lara awọn to doloogbe ọhun.

Nico ni: “Aigbọra-ẹni-ye lo kọkọ bẹrẹ, lo ba di ija, akọlu-kọgba si ṣẹlẹ. Niṣe lawọn alatilẹyin yii bẹrẹ si i kọlu awọn ọlọpaa, wọn ba mọto jẹ, ọpọ eeyan lo ṣubu sẹnu geeti nigba ti wọn n rọ jade, bi wọn ṣe n ṣubu ni wọn n tẹ wọn pa, tori niṣe ni wọn n ti ara wọn”.

Ninu fidio kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara nipa iṣẹlẹ ọhun, a ri awọn sọpọta kan ti wọn wọṣọ buluu, awọn keji si wọṣọ pupa foo, bẹẹ ni wọn ṣafihan bawọn tinu n bi naa ṣe n ba mọto jẹ, ti wọn n ba awọn dukia mi-in ati ẹṣọ papa iṣere naa jẹ pẹlu.

Wọn tun ṣafihan bi wọn ṣe n gbe awọn oku sinu apo igbokuu-si, wọn si n gbe awọn to fara pa digbadigba sinu ọkọ ambulansi lati gbe wọn lọ sọsibitu.

Ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alafẹsẹgba lorileede naa ti sọ pe awọn maa ṣewadii ijinlẹ nipa iṣẹlẹ yii lati mọ bọrọ naa ṣe jẹ gan-an.

Leave a Reply