Iku Timothy: Mọṣuari lọmọ Adedoyin sọ fun mi pe a n gbe oku rẹ lọ ko too ni ka ju u sẹgbẹẹ igbo- Kazeem

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila yii, ni wọn tun gbe Oloye Adedoyin, afurasi lori iku Timothy Adegoke, akẹkọọ Fasiti Ifẹ ti wọn pa si otẹẹli Hilton, to wa n’Ileefẹ.

Adedoyin pẹlu awọn ọmọọṣẹ rẹ mẹfa ni wọn jọ wa si kootu. Aṣọ funfun ni ọkunrin naa wọ, to si de fila bẹntigọọ si i.

Nigba ti idajọ bẹrẹ, olujẹjọ karun-un ninu ẹjọ to n lọ lọwọ nipa iku to pa Timothy Adegoke, nileetura Hilton, niluu Ileefẹ, loṣu Kọkanla, ọdun 2021, Kazeem Oyetunde, sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iku ọmọkunrin naa.

Kazeem to fara han ni kootu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun 2022, pẹlu Dokita Rahmon Adedoyin to ni ileetura naa atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa.

A oo ranti pe ẹlẹrii Adedoyin lo yẹ ko wa si kootu gẹgẹ bii ohun ti wọn fẹnu ko si nijokoo igbẹjọ to kọja, ṣugbọn ṣe ni agbẹjọro rẹ, K. K. Ẹlẹja tun sọ funle-ẹjọ pe olujẹjọ naa ti wa ni olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa niluu Oṣogbo, ati pe yoo fara han ni kootu laipẹ.

Ṣugbọn titi ti kootu fi pari, ẹlẹrii naa ti wọn pe ni ọlọpaa ko de. Bakan naa ni Ẹlẹja sọ pe awọn tun ti fi iwe pe ẹlẹrii mi-in, oun naa yoo si fara han ni kootu laipẹ.

Lasiko yii ni agbẹjọro fun olujẹjọ karun-un, Rowland Otaru, pe Kazeem, ẹni to jẹrii fun ara rẹ, bẹẹ ni agbẹjọro fun olupẹjọ naa, Fẹmi Falana SAN, naa tun beere oniruuru ibeere lọwọ rẹ.

Ninu ẹri rẹ, Kazeem Oyetunde, sọ pe laaarọ ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, ni alakooso ileetura naa, Raheem Adedoyin, to jẹ ọmọ Dokita Adedoyin, sọ fun oun ati Aderọgba pe oun (Raheem) ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti ni Mọọrẹ, wọn si ti ni ki awọn gbe oku rẹ lọ si mọṣuari.

O fi kun ọrọ rẹ pe bi awọn mẹtẹẹta ṣe gbe oku naa sinu Hilux alawọ funfun ti Raheem maa n lo, ni Raheem fori le ọna Ẹdẹ Road, nigba ti awọn si de ibi kan lo duro, to si ni ki awọn ju oku Timothy sẹgbẹẹ igbo.

O ni bi awọn ṣe fẹẹ gbe oku naa kuro ninu ileetura ni Raheem ti ko gbogbo kọmputa alaagbeka, foonu, owo, oogun oyinbo to lo ku ati omi to mu ku sinu baagi alawọ buluu kan, to si ju u sẹgbẹẹ oku Timothy lẹyin tawọn ju u sẹgbẹẹ igbo.

O ni bayii ni Raheem gbe awọn pada si otẹẹli, latigba naa loun ko si ti foju kan mọto Hilux naa atawọn ẹru Timothy mọ.

Nigba ti wọn beere idi ti Kazeem ko fi lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti, o ni ki i ṣe iṣẹ oun lati fi to awọn ọlọpaa leti nitori ọga oun ni Raheem jẹ.

Igbẹ ọdẹ lawọn ajinigbe lọ ti mo fi raaye sa mọ wọn lọwọ – Adejumọ

Leave a Reply