Ikunlẹ abiamọ o! Eeyan mejila jona ku nibi ijamba ọkọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Kwara

O kere tan, eeyan mejila lo pade iku ojiji lasiko ti ọkọ Dangote to ko simẹnti gbina lẹyin ti oun ati ọkọ ero bọọsi elero mejidinlogun kọ lu ara lopopona marosẹ Ẹyẹnkọrin si Ogbomoṣọ, lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassana Hakeem Adekunle, fi sita lọjọ Abamẹta, Satide, niluu Ilọrin, lo ti salaye pe ijamba ọkọ naa mu ẹmi eeyan mejila lọ loju ina, ti ajọ naa si doola ẹmi awọn to fara pa nipa gbigbe wọn lọ si ileewosan jẹnẹra tilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. O tẹsiwaju pe ọkan lara ero ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si sọ pe awọn gbera pẹlu ọkọ ero bọọsi naa niluu Eko, ti wọn si n lọ si ipinlẹ Sokoto, ko too di pe wọn pade ijamba ọhun ni Ẹyẹnkọrin, nipinlẹ Kwara, bo tilẹ jẹ pe wọn o mọ ohun to fa ijamba naa.

Adari ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Falade John Olumuyiwa, ti waa rọ gbogbo awọn awakọ lati maa tẹ ẹ jẹẹjẹ loju popo, paapaa ju lọ, ti wọn ba ko awọn ero sinu ọkọ wọn.

Leave a Reply