Faith Adebọla, Eko
Awọn ọmọde meji kan, Samat, ọmọọdun mẹsan-an, ati ẹni keji, Saheed, ti wọn ni ko ju ọmọọdun mẹta pere lọ, ti padanu ẹmi wọn nigba ti fẹnsi ileewe aladaani Covenant Point Academy, wo lu wọn mọlẹ l’Ekoo.
Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an yii, l’Opopona Ajọsẹ, lagbegbe Amukoko.
Wọn niṣe ni Samat n kọja lọ ni tiẹ, o gba ọna iwaju fẹnsi naa kọja sibi tawọn obi ẹ ran an, nigba ti ẹni keji n ṣere niwaju ọgba naa, tori ṣọọbu mama rẹ wa nitosi ibẹ, ko sẹni to fura pe ajalu kan fẹẹ ṣẹlẹ.
Ojiji ni fẹnsi naa ya lulẹ wii, bulọọku nla ti wọn to bii opo to wa lara ogiri naa ṣe kongẹ Samat, oju ẹsẹ lo ku. Wọn lọmọ keji ṣi japoro iku witiwiti, awọn aladuugbo si sare fa a yọ labẹ awoku naa, wọn du ẹmi ẹ boya wọn ṣi le rọgbọn da si i, ṣugbọn ko dele-iwosan to fi dakẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe awọn ọlọpaa ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti mu oludasilẹ ileewe ọhun.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ pe “ko si kọnkere tabi pila kankan lara ogiri naa, wọn ko si fi irin saarin ẹ lati fun un lagbara, bulọọku wẹwẹ ni wọn kan mọ leri ara wọn, wọn si dabuu bulọọku lati fi i ṣe opo saarin meji. Ko si nnkan to le di fẹnsi naa mu, eyi lo jẹ ko rọrun lati wo paayan.”
A gbọ pe niṣe lawọn obi ọmọọdun mẹsan-an naa bẹrẹ si i wa a kiri nigba ti wọn reti titi, ti ko de bọrọ lati ibi ti wọn ran an lọ, asiko naa ni wọn too gbọ pe ọmọ wọn ti ku sabẹ ẹbiti ọhun.
Alukoro ọlọpaa lawọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, awọn yoo si tuṣu desalẹ ikoko lati foju awọn to ba jẹbi ọran naa bale-ẹjọ.