Monisọla Saka
Amookunṣeka ẹda kan ti da ẹmi Arabinrin Tina Ileogben legbodo, lẹyin to gun un lọbẹ nibi ọna ọfun, lo tun yọ ọkan ẹ lọ.
Nile oloogbe to wa ni Olowo street, Alhaja Shifiwa, Dọpẹmu, Agege, nipinlẹ Eko, ni wọn ti ba oku obinrin to n ṣiṣẹ nileeṣẹ burẹdi ati ibi ti wọn ti n ṣe akara oyinbo yii.
Ọkan lara awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ lo wa a lọ sile ẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun yii, nigba ti wọn ko ri i nibi iṣẹ. Iyalẹnu lo jẹ nigba tonitọhun ba ilẹkun abawọle ẹ ni ṣiṣi gbayawu, nigba ti yoo si wọnu ile, ninu agbara ẹjẹ lo ba oku Tina ti wọn ti ṣe e yankanyankan.
Alabaaṣiṣẹpọ rẹ yii lo kegbajare ohun to ri fawọn araale, ti gbogbo wọn fi pe jọ sibẹ.
ALAROYE gbọ pe ẹyin ti ẹni to pa a fi ọbẹ la a lọna ọfun tan lo tọwọ bọ ẹyin ọrun mọ igbaaya rẹ lati yọ ọkan rẹ lọ.
Dokita to wa nibudo iṣẹlẹ naa tun fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn ti yọ ọkan ọmọbinrin naa lọ.
Lasiko ti wọn n yẹ inu ara ẹ wo fawọn ẹya ara ti wọn yọ lọ ni wọn ri i pe lasiko ti olubi ẹda yii n yọ ọkan Tina, o fọwọ ko diẹ lara ifun ẹ jade, eyi to kọ ọ lọrun.
Ẹgbọn oloogbe, Justina, to n pe fun idajọ ododo lori iku aburo ẹ ni wọn ti kọkọ fipa ba aburo oun lo pọ ki wọn too gbẹmi ẹ, nitori gbogbo inu ile ẹ lo kun fun ẹjẹ.
“Mo ti ku tan bi mo ṣe wa yii. Ile ni mo wa ti wọn pe mi pe aburo mi ṣubu, ati pe o ṣe pataki ki n yọju kia. Loju-ẹsẹ naa ni mo ti sare wa sile ọdọ ẹ.
“Ẹru ba mi nigba ti mo ba ero rẹpẹtẹ nibẹ. Ara fu mi pe nnkan buruku ti ṣẹlẹ, mo bẹrẹ si i sunkun, mo sare pada si ṣọọbu mi. Mo kan tun ṣe ọkan mi giri, ni mo ba pada wọnu ile ẹ lati gan-an-ni ohun to ṣẹlẹ, afi bi mo ṣe ri oku ẹ.
“Gbogbo ilẹ, ara ogiri ati ori bẹẹdi rẹ lo kun fun apa ẹjẹ balabala. Nigba ti mo sun mọ oku ẹ ti mo wo o daadaa, mo ri i pe ẹni yẹn fipa ba a lajọṣepọ ko too pa a ni. Ẹni yẹn fi ọbẹ la ọna ọfun ẹ, lẹyin naa ni wọn yọ ọkan ẹ lọ”.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe, “Ọkunrin kan to n jẹ Akeem, ọkan lara awọn alabaaṣiṣẹpọ oloogbe ati onile wọn ni wọn mu ẹjọ ọrọ naa wa si agọ ọlọpaa Dosunmu. O yẹ ki oloogbe wa nibi iṣẹ lọjọ naa, ṣugbọn nigba ti wọn ko ri i, ni ọkan lara awọn to jẹ ọga fun wọn nibẹ sọ pe ki Akeem lọọ wo o, niwọn igba ti ile rẹ ko jinna sibi iṣẹ wọn.
“Amọ nigba ti yoo debẹ, ṣiṣi ni Akeem ba yara ẹ, oun pẹlu awọn meji ti wọn jẹ araale Tina ni wọn jọ wọle ti wọn ba oku Tina nihooho goloto ninu agbara ẹjẹ pẹlu ọrun ẹ ti wọn ti fi ọbẹ la.
Iwadii ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa. Lori ọrọ ọkan rẹ ti wọn ni wọn yọ kuro, ko sohun to jọ bẹẹ”.
Hundeyin sọ siwaju si i pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ayika nipinlẹ Eko, Lagos State Environmental Health Monitoring Unit, ti gbe oku obinrin naa lọ si ile iwosan ijọba, Mainland General Hospital, Yaba, fun ayẹwo iku to pa a.