Faith Adebọla
Iran buruku niran ọhun, ko ṣee duro wo rara, nigba tawọn agbofinro atawọn ẹṣọ alaabo n sa ajoku oku awọn akẹkọọ ileewe sẹkọndiri Mahdia, iyẹn Mahdial Secondary School, jade, tẹkun-tomije lawọn obi ati mọlẹbi awọn majeṣin fi n kawọ mọri, ti wọn n ṣedaro pẹlu ọkan to gbọgbẹ gidi lori ajalu buruku ọhun.
Ilu Mahdia, to wa l’Aarin-gbungbun Guyana, lorileede Guyana, niṣẹlẹ naa ti waye lọganjọ oru ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un yii, mọju ọjọ Aje, Mọnde, to tẹle e.
Ba a ṣe gbọ, inu ọgba ileewe sẹkọndiri ọhun lawọn akẹkọọ naa n gbe, tori ilegbee wa lẹgbẹẹ awọn yara ikawe wọn. Ko si sẹni to fura pe ajalu kan yoo ṣẹlẹ titi ti kaluku fi kọja sori bẹẹdi koowa wọn lalẹ ọjọ Sannde naa.
Ninu atẹjade kan tawọn alaṣẹ ilu orileede naa fi lede laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un yii, wọn ni nnkan bii aago mejila oru ku iṣẹju diẹ ni ina naa bẹrẹ, ati pe ọ jọ pe ọdẹdẹ ilegbee awọn ogowẹẹrẹ ọhun ni ina naa ti bẹrẹ, eefin apọju ni wọn lo ṣee ko fi awọn ọmọ ọhun pa, ti ko fi ṣee ṣe fun pupọ ninu wọn ribi sa asala ti ina ọmọ ọrara ọhun fi ka wọn mọ.
A gbọ pe awọn ọmọ kan ṣi wa, yatọ sawọn ti wọn ti ri oku wọn yii, ti wọn o ti i mọ ibi ti wọn ha si, boya wọn ti ba iṣẹlẹ ọhun ri ni o, abi wọn ṣi wa nibi kan teeyan o mọ.
Baaluu awọn oṣiṣẹ eleto ilera orileede naa nijọba lọọ fi ko awọn tori ko yọ ninu ijamba naa, amọ ti ọpọ ninu wọn ti fara pa yanna-yanna.
Aarẹ orileede Guyana, Irfaan Ali, ti ṣapejuwe ijamba yii gẹgẹ bii iṣẹlẹ to buru balumọ, o ni eyi ki i ṣe iṣẹlẹ bintin rara, o si kede rẹ gẹgẹ bii ajalu gboogi ninu itan orileede rẹ. O lo ka oun lara gidi, o si dun oun wọnu egungun pẹlu.
“A o maa gbadura s’Ọlọrun Ọba pe ki aanu ati itunu rẹ wa pẹlu awọn obi, mọlẹbi, ọrẹ ati awọn aladuugbo ti eeyan wọn fara gba ninu ajalu meriiyiri yii,” gẹgẹ bi Aarẹ wọn ṣe sọ.