Faith Adebọla
Orin ‘emi la o ni i yọ si, ba a ṣe fẹ ko ri bẹẹ naa lo ri’, lo gbẹnu oludije funpo gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ọsun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ, Peoples Democratic Party (PDP) kan, nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, latari idajọ ile-ẹjọ giga apapọ to wọgi le iyansipo Gomina Isiaka Oyetọla ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) gẹgẹ bii oludije funpo gomina ninu eto idibo to kọja loṣu keje ọdun 2022, ati Igbakeji rẹ, Benedic Alabi. Wọn lawọn mejeeji ko lẹtọọ lati kopa ninu eto idibo naa rara, tori bi wọn ṣe fa wọn kalẹ ko bofin mu pẹẹ.
Idajọ yii waye ninu ẹjọ kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe ta ko Gomina Mai Mala Buni, ti ipinlẹ Yobe, gẹgẹ bii alaga igbimọ kiateka to n tukọ ẹgbẹ oṣelu naa lasiko ti wọn fi fa Oyetọla kalẹ lati dije funpo gomina.
Iwe ipẹjọ ọhun, eyi ti lọọya PDP, Amofin agba Kẹhinde Ogunwomiju, fi siwaju ile-ẹjọ giga to fikalẹ siluu Abuja lọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii, fẹsun kan Buni pe, bo ṣe jẹ oun lo buwọ lu fọọmu iyansipo Oyetọla ati igbakeji rẹ gẹgẹ bii oludije, to si fi fọọmu naa ṣọwọ si ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ko tọna rara, o ni igbesẹ naa tẹ ofin loju gidi, tori isọri kẹtalelọgọsan-an iwe ofin ilẹ wa, ati isọri kejilelọgọrin, ila kẹta, ninu iwe ofin eto idibo tọdun 2022 ko faaye gba iwa ti Buni, ẹgbẹ APC, atawọn oludije wọn hu naa.
Amọ, lasiko igbẹjọ, agbẹjọro olujẹjọ, Amofin agba Kunle Adegoke, to duro fun Buni, Oyetọla ati APC, sọ pe ẹjọ raurau ni ẹjọ naa, o ni ọrọ ti ọjọ ti lọ lori ẹ ni ẹjọ ti PDP n ran-angun apa le lori ọhun, tori Buni ko ṣẹṣẹ di alaga kiateka, eyi si kọ nigba akọkọ to maa forukọ awọn oludije ṣọwọ si INEC, ati pe olupẹjọ naa ko laṣẹ lati pe iru ẹjọ to pe yẹn, tori ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ APC, ko si yẹ kọrọ naa kan wọn rara, ayọjuran lasan ni wọn fẹẹ ṣe, tori ẹ, o rọ ile-ẹjọ pe ki wọn da ẹjọ naa nu bii omi iṣanwọ ni, tori ifakoko ṣofo lo maa ja si.
Ṣugbọn olujẹjọ naa ni ọrọ ofin lọrọ to delẹ yii, ile-ẹjọ si gbọdọ jẹ ka mọ ohun tofin sọ lori ẹ ni.
Ṣa, lẹyin atotonu ati awijare olupẹjọ ati olujẹjọ, adajọ kootu naa, Emeka White, sọ pe ko sọrọ ayọjuran rara ninu ẹjọ ti olupẹjọ pe, tori wọn lẹtọọ lati beere lọwọ ile-ẹjọ nipa ohun ti ofin sọ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, White ni oun ti gbọn awọn iwe ofin wo yẹbẹyẹbẹ, ko si ibi ti ofin yọọda fun ẹnikan to wa nipo alakooso ipinlẹ gẹgẹ bii gomina lati tun di ipo alakooso ẹgbẹ oṣelu mu gẹgẹ bii alaga igbimọ afun-un-sọ. O ni bi Gomina Mai Mala Buni ṣe dipo mejeeji mu ko bofin mu rara, tori naa, gbogbo aṣẹ ti ọkunrin naa pa, ati igbesẹ to gbe gẹgẹ bii alakooso ẹgbẹ APC lasiko naa lo lodi patapata, gbogbo ẹ si lofin wọgi le.
O ni loju ofin, bii igba teeyan n yin agbado sẹyin igba ni fifi ti Buni forukọ Oyetọla ati Alabi ṣọwọ gẹgẹ bii oludije funpo gomina ati igbakeji gomina jẹ, awọn mejeeji ko lẹtọọ lati kopa ninu eto idibo naa, tori ẹni to forukọ wọn ṣọwọ rufin ni.
Ni bayii, afaimọ ni idajọ yii ko ti ṣẹ Gomina Oyetọla ati ẹgbẹ APC rẹ leegun ẹyin lori ẹjọ mi-in ti wọn pe tako bi Ademọla Adeleke ṣe jawe olubori ninu eto idibo to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje naa, wọn niṣe nidaajọ yii maa mu k’ẹjọ ku s’Ake.