Ile-ẹjọ da Gomina Adeleke lare

Florence Babaṣọla

Ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ti fi ọwọ osi da idajọ to kọkọ waye nipinlẹ Ọṣun, nibi ti ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun to ba su yọ lasiko idibo ti sọ pe Oyetọla ni ko pada sipo nu, wọn ni ko sohun to jọ ọ, bẹẹ ni wọn fi ontẹ lu u pe Gomina ipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ, Ademọla Adeleke, lo bori idibo ti wọn ṣe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun to kọja, nipinlẹ naa, wọn ni ko maa ba ijọba rẹ lọ.

Lasiko igbẹjọ naa to waye ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii ni wọn gbe idajọ naa kalẹ nile-ẹjọ ọhun to wa niluu Abuja.

Ninu igbimọ ẹlẹni mẹta to gbe idajọ naa kalẹ, eyi ti Onidaajọ Muhammed Shuaibu dari ni wọn ti fẹnu ko pe Adegboyega Oyetọla ati ẹgbẹ APC ko ni ẹri to to lati fi han pe adiju ibo waye lasiko eto idibo naa.

Ninu idajọ naa ti nọmba rẹ jẹ CA/AK/EPT/GOV/01/2023 ni wọn ti sọ pe ko tọna bi i ijokoo ile-ẹjọ akọkọ ṣe gba ọrọ ti awọn ẹlẹrii sọ nikan gbọ pe adiju ibo wa lawọn ibi kan wọle lai jẹ pe wọn wo akọsile iwe eto idibo ati ẹrọ to n gba aworan ati orukọ awọn oludibo silẹ ti wọn n pe ni BIVAS. Wọn ni iwe iforukọsilẹ awọn oludibo lo ṣe pataki, to si jẹ ipinlẹ akọkọ  ninu eyikeyii idibo, eyi naa lo si yẹ ki wọn ṣamulo, ki i ṣe ohun ti awọn ẹlẹrii sọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun to kọja, ni eto idibo gomina waye nipinlẹ Ọṣun, lẹyin eto idibo naa ni ajọ eleto idibo kede Ademọla Adeleke gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna irinwo le mẹta ati diẹ (403, 371), nigba ti Oyetọla ni ibo ẹgbẹrun lọna ọrinlenirinwo din marun-un ati diẹ (375, 027).

Ṣugbọn ni kete ti esi idibo yii jade ni Oyetọla ati ẹgbẹ oṣelu APC ti gba ile-ẹjọ lọ, wọn ni awọn lawọn bori eto idibo naa, ki ile-ẹjọ gbe ikede ajọ eleto idibo ti sẹgbẹẹ kan, ki wọn si gba iwe-ẹri ti wọn fun Adeleke, ki wọn da a pada fun Oyetọla.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii ni idajọ naa waye, eyi ti Onidaajọ Tertse Kume ati awọn igbimọ rẹ gbe kalẹ pe adiju ibo wa lawọn ijọba ibilẹ kan, ati pe nigba tawọn yọ awọn adiju ibo naa kuro, Oyetọla lo bori. Ṣugbọn ọkan ninu awọn onidaajọ naa, Adajọ Ogbuli sọ pe oun ko fara mọ idajọ naa, o ni loju toun, Adeleke lo wọle ibo ọhun.

Idajọ yii lo mu Adeleke gba ile-ẹjọ Kotẹmilọrun lọ, nibi to ti ni ki wọn tun ba awọn fi oju agba wo idajọ ti ile-ẹjọ takọkọ da.

Ile-ẹjọ naa ti waa sọ pe ki ọkunrin naa maa ba ijọba rẹ lọ nipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii gomina ti wọn dibo yan. Wọn ni Oyetọla ati ẹgbẹ APC ko ni ẹri to to lati sọ pe adiju ibo waye nitori wọn ko wo iwe ti wọn fi kọrukọ awọn oludibo sile, ọrọ awọn ẹlerii nikan ni wọn gbe idajọ wọn le lori.

Afi bii oju ogun ni kootu naa ri laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ti idajọ naa waye. Niṣe ni awọn agbofinro kun ibẹ girangiran, lati pese aabo, ati lati ri i pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ. Bẹẹ ni awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu mejeeji kun inu ọgba ile-ẹjọ naa lati wo bi nnkan ṣe n lọ.

Leave a Reply