Ile-ẹjọ ju Doyin Okupe, ọga agba ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ Labour sẹwọn ọdun meji ataabọ

Jọkẹ Amọri

Ẹwọn ọdun meji ataabọ ni Adajọ ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja, Onidaajọ Ijeoma Ojukwu, ju Ọga agba fun eto ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Doyin Okupe, si lori ẹsun pe o ṣe arọndarọnda owo, eyi ti wọn lo lodi sofin ti wọn fi lelẹ lori gbigbe owo kaakiri(Money Laundaring).

 Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila yii, ni adajọ kede pe o jẹbi ẹsun naa. Wọn lo gba ju owo ti ofin fi lelẹ lati gba lọ, bẹẹ ni ko si gba ọna to yẹ labẹ ofin lati ṣe eleyii. Adajọ ni ẹnikẹni ko lẹtọọ labẹ ofin lati gba ju miliọnu arun-un si mẹwaa Naira lọ, ẹni to ba fẹẹ ṣe bẹẹ gbọdọ gba aṣẹ lọwọ ileeṣẹ to ni i ṣe pẹlu ọrọ owo nina (financial Institution) ṣugbọn Okupe ko ṣe eleyii.

Ẹsun mẹrindinlọgbọn ninu mọkandinlọgọta ti ileeṣẹ to n ri si ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati iwa ajẹbanu (EFCC), fi kan an ni kootu ni o jẹbi rẹ.

Ẹsun kọkọkan ni adajọ ni yoo lo ọdun meji ataabọ fun lọgba ẹwọn, ṣugbọn yoo ṣe gbogbo ẹwọn yii papọ ni, eyi to fi ku si ọdun meji ataabọ.

Tẹkuntẹkun ni iyawo atawọn ọmọ Okupe fi n bẹ adajọ pe ko ṣiju aanu wo ọkunrin naa. Nidii eyi, ni Onidaajọ Ojukwu fi ni ko lọọ san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira fun ẹsun kọọkan, eyi to ku si miliọnu mẹtala Naira. O fi kun un pe ti ko ba tete ri owo naa san, ki wọn maa gbe e lọ si ọgba ẹwọn Kuje.

Tẹ o ba gbagbe, ọdun ni 2019 ni EFCC wọ Okupe lọ sile-ẹjọ lori ẹsun mọkandinlọgọta ti wọn fi kan an pe o ṣe arọndarọnda miliọnu mejilelẹẹẹdẹgbẹrin (702m). Wọn ni o gbowo lọwọ oludamọran aarẹ ilẹ wa tẹlẹ lori eto aabo, Sambo Dasuki, eyi ti ile-ẹjọ ni o pọ ju iye to jẹ ko fọwọ gba labẹ ofun lọ. Ileeṣẹ meji kan, Value Trust Investment Limited ati Abrahams Telcoms Limited ni wọn jọ gbe wọn lọ sile-ẹjọ lasiko naa.

Leave a Reply