Ile-ejọ kankan ko le da eto ibura sipo Tinubu duro-Ijọba apapọ

Adewale Adeoye

Ni bayii, awọn alaṣẹ ijọba apapọ orileede yii ti sọ ọ di mimọ pe ko sohun naa to le di awọn lọwọ lati ma ṣe bura fun aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorileede yii ninu ibo to waye, lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, bi akoko ba to gan-an.

Wọn ni koda ileejọ paapaa ko le paṣẹ rẹ pe ki eto ibura sipo aarẹ fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ma waye rara.

Ẹni to sọrọ yii di mimọ ni Akọwe agba fun ijọba apapọ, Boss Mustapha, lakoko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja, lori ipinnu awọn alaṣẹ ijọba apapọ lori bawọn kan ṣe gbe Tinubu lọ si kootu, ti wọn si n rọ awọn adajọ gbogbo pe ki wọn da eto ibura sipo aarẹ naa duro titi di akoko ti ileejọ yoo fi sọ ẹni to wọle sipo ọhun.

Boss Mustapha to tun jẹ alaga igbimọ ti wọn yan lati ri i daju pe agbara paarọ ọwọ fun ijọba tuntun to n bọ lọna yii sọ pe ko sohun naa to le di ọjọ ti eto ibura sipo naa maa waye lọwọ rara, nitori pe eyi ki i ṣe igba akọkọ rara tawọn kan maa pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun fun bi wọn ṣe kede pe aarẹ kan lo wọle lorileede yii.

O ni, ‘Ohun tawọn kan ko mọ rara ni pe ko sohun naa to maa da eto ibura sipo fun Tinubu ti wọn ṣẹṣẹ yan ati igbakeji rẹ, Shettima, duro. Awọn kan naa gbe aarẹ Shehu Shagari lọ si kootu pe oun kọ lo wọle nigba yẹn, ẹjọ wa ni kootu, bẹẹ ni wọn ṣeto ibura fun Shagari nigba yẹn, bakan naa lo tun ri nigba ijọba Oluṣegun Ọbasanjọ, awọn kan ti esi ibo to gbe e wọle ko tẹ lọrun gbe ẹjọ won lọ si kootu, ṣugbọn ṣe lawọn alaṣẹ ijọba akoko naa ṣeto ibura fun Baba Iyabọ, to si di aarẹ nigba naa lọhun-un.

Aarẹ Jonathan nikan ṣoṣo ni ko gbe Buhari lọ si kootu nigba tiẹ. Fun idi eyi, ko sohun naa rara labẹ ofin ilẹ wa to maa di wa lọwọ pe ka ma seto ibura fun Tinubu ati igba keji rẹ bi akoko ba to.

Boss Mustapha ni iwe ofin ilẹ wa ọdun 1999 faaye gba a, to si tun sọ bi wọn yoo ṣe ṣohun gbogbo bi akoko ba to fohun to n ṣẹlẹ yii.

Nipari ọro rẹ, Akọwe naa sọ pe aimọye awọn olori orileede gbogbo lagbaaye ati nilẹ Adulawọ ni wọn ti fife han lati wa nibi eto ibura fun Tinubu, eyi ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii niluu Abuja.

Leave a Reply