Ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ti tu Kanu silẹ o

Jọkẹ Amọri

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa yii, ni ile-ẹjọ Kotẹmilọrun to fikalẹ siluu Abuja da ajijagbara ọmọ ilẹ Ibo to tun n ja fun ominira ilẹ Biafra nni, Nnamdi Kanu, lare, wọn ni ko maa lọ sile rẹ lalaafia.

Agbẹjọro rẹ to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Ifeanyi Ejiofor, lo sọ eyi di mimọ lori ikanni agbọrọkanye ta a mọ si Facebook rẹ.

Ile-ẹjọ ni Kanu wẹ, o yan kan-in-kan-in, ninu ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to pe lori awọn ẹsun afẹmiṣofo tijọba apapọ ilẹ wa fi kan an.

Gbogbo ẹjọ ati ẹsun ti ijọba apapọ fi kan ọkunrin ajijagbara yii ni Onidaajọ Oludọtun Adebọla fọwọ osi taari danu, o ni awọn ẹsun yii ko kun oju oṣuwọn, bẹẹ ni ko ba ofin mu.

Ile-ẹjọ yii ni ko tọna, o tun lodi sofin bi wọn ṣe mu ajijagbara naa lati orileede Kenya wa si ilẹ Naijiria, ti wọn si ju u satimọle latigba naa.

Adajọ ni gbogbo ofin nilẹ yii ati kaakiri agbaye ni ijọba apapọ lodi si pẹlu bi wọn ṣe fi ọkunrin naa sọko si Naijiria ni tipatipa, eyi to mu ki ẹsun afẹmiṣofo ti wọn fi kan an ma lẹsẹ nilẹ.

Adajọ Adebọla ni ọna aibofin-mu ti wọn gba gbe ọkunrin naa wa si Naijiria ti mu ki ẹjọ ti wọn pe e ja si otubantẹ, ti ko si ṣee ro nibikibi,.

Siwaju si i, adajọ ni pẹlu bi ijọba apapo ko ti le fidi ibi to ti ṣẹ awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii ati asiko to ṣe e mulẹ mu ki ẹjọ naa da bii atele ro, ti ko lẹsẹ nilẹ rara.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ajijagbara ọmọ ilẹ Ibo naa pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori ẹsun pe afẹmiṣofo ni ti ijọba apapọ fi kan an.

Ṣugbọn ni bayii, atẹgun alaafia ti ẹ si i, Adajọ Adebọla ni ko maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia.

Leave a Reply