Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Abidemi Rufai, ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹẹ Gomina Dapọ Abiọdun tẹlẹ yoo ṣi wa lẹwọn titi di ọjọ kin-in-ni, oṣu keji, ọdun 2022, gẹgẹ bi kootu ilẹ Amẹrika ti paṣẹ lori ọkunrin ti wọn lo lu jibiti owo nla lori ayelujara naa.
Adajọ Benjamin Settle, ti ile-ẹjọ kan ni Tacoma, lorilẹ-ede Amẹrika, lo paṣẹ yii nigbẹjọ to waye laipẹ yii.
Adajọ Settle ṣalaye pe o di dandan lati sun igbẹjọ Rufai si ọna jinjin bii eyi, ki awọn ti wọn n ṣewadii ẹ le raaye tu u palẹ daadaa, nitori ẹsun ti wọn fi kan an lagbara ju ki wọn kan sare ṣe e laarin asiko perete lọ.
Oju-ewe mẹtadinlọgọrun-un (97 pages) ni wọn fi kọ awọn ẹsun ti wọn fi kan Abidemi Rufai si. Awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu owo ijọba ilẹ Amẹrika atawọn orilẹ-ede mi-in kaakiri.
Ṣe lọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un, ọdun 2021, ni wọn mu ọkunrin yii lasiko to n gbiyanju lati fi orilẹ-ede New York silẹ. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o wọ irinwodinlaaadọta owo dọla (350,000) jade ninu apo asuwọn ijọba ilu naa, bẹẹ, owo iranwọ ti wọn fẹẹ fun awọn eeyan wọn lasiko ti Korona n ṣọṣẹ gidi lọdun 2020 ni.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹjọ yii, ni wọn fi igbẹjọ mi-in si tẹlẹ, ṣugbọn ayipada ti de ba ọjọ naa bayii, o ti di ọjọ kin-in-ni, oṣu keji, ọdun 2022. Ṣugbọn titi digba naa, ẹwọn ni Adajọ ni ki Rufai wa, ko maa ṣe faaji ẹ lọ.