Ile-ẹjọ ni kiyawo to fẹẹ kọ ọkọ ẹ sile da owo-ori to gba pada fun un

Adewale Adeoye
A ki i jẹ meji laba Alade ni adajọ ile-ẹjọ Sharia kan, Onidaajọ Malam Muhammad Adamu-Shehu, fọrọ naa ṣe pẹlu bo se paṣẹ fun ìyáálé ilé kan to fẹẹ kọ ọkọ rẹ pe ko da owo-ori ti ọkunrin naa san pada fun un. N lọrọ ba di bi ẹbiti ko ba p’eku, ko f’ẹyin f’ẹlẹyin ni.
Nipinlẹ Kaduna ni Abilekọ Fatima ti wọ ọkọ rẹ lọ si kootu to n gbọ ejo tọkọ-tiyawo, to si sọ pe oun ko fẹ ọkunrin naa mọ.
Abilekọ Fatima ni, ‘Oluwa mi, ọrọ ifẹ ọkọ mi yii ti su mi patapata, mi o nifẹẹ rẹ mọ rara, mi o si le jẹ oloootọ si i mọ, mo n rọ ile-ẹjọ yii pe ko tu igbeyawo to wa laarin awa mejeeji ka ni kia. Mo si fẹ ki ẹ gba mi laaye ki awọn ọmọ ti mo bi fun un wa lọdọ mi, ki n le maa tọju wọn.
Nigba to n fesi si alaye obinrin to fẹẹ koko yii, adajọ ni ki Abilekọ Fatima ma ṣẹṣẹ laagun jinna lori aba pe o fẹẹ kọ ọkọ rẹ. O ni niwọn igba ti Abilekọ Fatima ko ti nifẹẹ ọkọ rẹ mọ, ki i ṣe dandan pe ki wọn fipa fẹ ara wọn rara gẹgẹ bi lọọya ọkọ rẹ ṣe n bẹ iyaale ile naa.
Bo tilẹ jẹ pe ọkọ Fatima ko si nile-ẹjọ naa lakooko ti igbẹjọ n lọ lowọ, lọọya rẹ, Ọgbẹni L.R Ibrahim, rọ kootu naa pe ko ma ti i tu igbeyawọ naa ka rara, nitori pe ọkọ Fatima ṣi nifẹẹ rẹ gidigidi, o ni ki wọn ṣe suuru lori ẹjọ naa pe o ṣee ṣe ki Abilekọ Fatima ronu piwada lori ohun to n sọ yii.
Ninu idajọ rẹ ni Malam Muhammad ti paṣẹ pe niwọn igba ti Abilekọ Fatima ko ti nifẹẹ ọkọ rẹ mọ, ko da owo-ori ti ọkuunrin naa san nigba to fẹẹ fẹ ẹ pada fun un.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ mi-in.

Leave a Reply