Ile-ẹjọ ni loootọ ni Adedoyin lọwọ ninu iku Timothy Adegoke

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
 
Beeyan ba ju abẹrẹ silẹ, ketekete ni yoo maa gbọ ohun abẹrẹ naa nile-ẹjọ giga kan to wa ni agbegbe Oke-Fia, niluu Oṣogbo, nibi ti idajọ lori awọn ti wọn fẹsun kan nipa Timothy Adegoke, ọmọkunrin akẹkọọ Fasiti Ifẹ ti wọn pa si oteẹli Hilton, to jẹ ti Rahman Adedoyin ti n waye lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, ti waye.

 Ni nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju mejila ni Onidaajọ Adepele Ojo wọle si kootu ọhun, to si jokoo tepọn lori aga idajọ.

 Barisita Farimah Adeṣina lo ṣoju awọn olupẹjọ ni kootu ọhun.

Williams Ajayi lo ṣoju olujẹjọ kin-in-ni, nigba ti Henry Ọdunayọ ṣoju awọn olugbẹjọ keji, kẹta ati ikarun-un. Agbẹjọro Okon lo ṣoju olujẹjọ keje.

 Lori ọrọ pe agbẹjọro awọn olujẹjọ, iyẹn Fẹmi Falana, ko gba asẹ latọdọ kọmiṣanna fun eto idajọ nipinlẹ naa ko too bẹrẹ si i gba ẹjọ ro fun awọn olupẹjọ ni adajọ naa kọkọ sọrọ le lori  ni nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju mọkandinlogun.

 Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Ojo ni ko pọn dandan ki lẹta wa latọdọ kọmiṣanna feto idajọ lati sọ pe agbẹjọro kan n ṣoju oun, niwọn igba to ba ti fara han nile-ẹjọ, to si sọ pe oun n ṣoju ileeṣẹ eto idajọ, adajọ yoo gba a, niwọn igba ti ko ba ti ṣe nnkan ti ko tọ.

O ni Falana ati agbẹjọro to ba wa lati ọfiisi rẹ lagbara lati gba ẹjọ ro fun olupẹjọ, ti ko si si ẹni to maa yẹ wọn lọwọ rẹ wo.

Aago mọkanla ku iṣẹju meje ni Onidaajọ agba bẹrẹ idajọ rẹ. Awọn olupẹjọ pe ẹlẹrii mẹjọ. Lara ẹsun ti wọn fi kan awọn olujẹjọ ni igbimọ-pọ lati huwa buburu, pipa Adegoke, hihuwa buburu si oku ọmọkunrin naa, gbigbe mọto Hilux ti wọn fi gbe oku Adegoke sọnu sa lọ si Abuja, igbimọ-pọ lati bura, igbimọ-pọ lati ji foonu, ẹrọ alaagbeletan ati pọọsi Adegoke. Igbimọ-pọ lati gbe igbesẹ ti yoo fi da bii ẹni pe Adegoke ko sun sinu oteẹli wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Onidaajọ Adepele sọ pe ko si ariyanjiyan nibẹ pe inu yara karunlelọọọdunrun otẹẹli Hilton, ni Timothy ku si laarin ọjọ karun-un si ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Bakan naa ni adajọ ni awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe loootọ lawọn olujẹjọ gbimọ-pọ lati pa Timothy Adegoke.

Siwaju si i, ẹri tun fi han pe Dokita Rahmon Adedoyin wa ninu otẹẹli lọjọ ti Timothy dawati , oun lo si sọ fun ọkan lara awọn oṣiṣẹ rẹ pe ko sọ fun ọlọpaa pe Timothy ko sun sọdọ awọn, bẹẹ loun gan-an ko si wi awijare kankan lori eleyii, eyi to tumọ si pe oun naa gba pe loootọ ni gbogbo nnkan tawọn oṣiṣẹ rẹ sọ nipa ẹsun naa.

Ile-ẹjọ gba pe loootọ ni Adedoyin jẹbi ẹsun igbimọ-pọ lati pa Timothy, o si lọwọ ninu iku Adegoke.

Leave a Reply