Adewumi Adegoke
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla yii, ni Adajọ Inyang Ekwo, ti ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja, paṣẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), pe ki wọn ṣilẹkun ọfiisi wọn pada fun awọn araalu to ba fẹẹ forukọ silẹ lati gba kaadi idibo, ki wọn si tẹsiwaju ninu fifi orukọ wọn silẹ. Eto yii ni wọn ni o gbọdọ ṣẹṣẹ wa sopin ni o ku aadọrun-un ọjọ ti eto idibo yoo bẹrẹ.
Idajọ yii ko sẹyin ẹjọ kan ti Anajat Salmat ati awọn mẹta mi-in pe ajọ eleto idibo lori bi wọn ṣe tete fopin si iforukọ silẹ awọn araalu lati gba kaadi idibo wọn, wọn ni ko tọna, nitori wọn ko tẹle ohun ti ofin ilẹ wa sọ lori eleyii..
Ninu idajọ rẹ, Adajọ Inyang ni ojuṣe ajọ eleto idibo ni labẹ ofin lati ri i pe wọn pese anfaani ati asiko to to fun awọn araalu lati ri i pe wọn gba kaadi idibo wọn. O fi kun un pe ki wọn ri i pe wọn ko du awọn eeyan orileede yii to ti to lati dibo ni anfaani lati gba kaadi naa, ki wọn le raaye ṣe ojuṣe wọn.
Ajọ Akoroyin jọ ilẹ wa ṣalaye pe, ninu iwe ti awọn eeyan naa fi pe ajọ eleto idibo lẹjọ ni wọn ti n beere pe ko yẹ ki INEC fopin si iforukọsilẹ naa lai ti i to asiko ti ofin ilẹ wa la kalẹ. Eyi ni wọn fi rọ ile-ẹjọ pe ki wọn paṣẹ fun wọn lati bẹrẹ iforukọ silẹ pada titi ti yoo fi ku aadọrun-un ọjọ ti eto idibo yoo waye gẹgẹ bi ofin ilẹ wa ṣe sọ.
Adajọ ni lori pe ẹtọ ni ohun ti awọn eeyan naa n beere fun labẹ ofin loun fi gbe idajọ yii kalẹ.