Ile-ẹjọ ran ayederu lọọya lẹwọn l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Mijisireeti kan to wa l’Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, ti ran ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji kan, Abayọmi Kayọde lẹwọn ọṣun mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara, lori ẹsun pe o pe ara rẹ ni agbẹjọro.

Awọn agbẹjọro ẹkun Ikẹrẹ-Ekiti lo mu ọkunrin naa, ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ pẹlu ẹsun pe o funra rẹ ṣe agbelẹrọ ontẹ ati siili awọn agbẹjọro niluu naa, lẹyin to parọ pe oun lọ sileewe giga Yunifasiti ipinlẹ Ekiti.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Taofeek Ọla-Ọlọrun sọ pe ọdaran naa jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan, o si paṣẹ pe ko san ẹgbẹrun lọna àádọta Naira lori ẹsun kọọkan tabi ko lọ ṣewọn ọṣun mẹfa gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.

Ṣaaju ni agbẹjọro fun ayederu lọọya yii, Ọgbẹni Tọpe, ti bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ fi onibaara oun silẹ lẹin to ti gba pe loootọ loun ṣẹ ẹṣẹ naa, o si tun tọrọ aforiji lọwọ ile-ẹjọ naa.

Ṣugbọn gbogbo ẹbẹ ti agbẹjọro yii bẹ, niṣe lo gba ẹyin eti ile-ẹjọ naa lọ.

Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ naa, Alaga awọn agbẹjọro ni ẹkun Ikẹrẹ-Ekiti, Arabinrin Kẹkẹ Owolabi, sọ pe ayederu agbẹjọro yii ti di ẹlẹwọn, bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ fun ni aaye lati san owo itanran. O ni eleyii yoo kọ awọn ayederu lọọya ti wọn n ba iṣẹ agbẹjọro jẹ lọgbọn.

Leave a Reply