Ile-ẹjọ sọ Ademọla sẹwọn, iṣẹ ẹjẹnti lo fi lu awọn eeyan ni jibiti owo nla l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ahamọ ọgba ẹwọn nile-ẹjọ Majisreeti to wa n’Igboṣere, l’Ekoo, sọ Adeyẹmi Ademọla si. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o loun n ṣiṣẹ ẹjẹnti lati ba awọn ayalegbe wa ile, ṣugbọn jibiti lo n lu wọn, miliọnu lọna ogun naira ni gbese ti wọn ṣẹ si i lọrun bayii.

Agbefọba, Inpẹkitọ Franscis Igbinosa, ṣalaye fun ile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba ti igbẹjọ waye lori ẹsun yii, pe laarin ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2017, si ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun naa, ni afurasi ọdaran yii huwa aidaa ọhun.

Alaye to ṣe ni pe, ile kan wa ti wọn pe ni Richland Mall and Event Centre, loju ọna Lẹkki si Ajah, lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko, Ọtunba Stephen Ajọsẹ lo ni ile naa, ṣọọbu rẹpẹtẹ ni wọn n kọ sibẹ, ni Ademọla ba n sọ fawọn eeyan pe wọn oun ni aṣoju ẹni to ni ṣọọbu naa, kawọn eeyan to ba fẹẹ rẹnti ṣọọbu naa tete kowo wa.

Wọn lo gba miliọnu kan naira lọwọ Ọgbẹni Kenneth Okpaise tiyẹn loun fẹẹ rẹnti ṣọọbu kan, o gba miliọnu kan ati okoolelọọọdunrun naira lọwọ Ọgbẹni Emmanuel Ibenye logunjọ, oṣu kẹsan-an, bẹẹ lo tun gba miliọnu mẹwaa aabọ lọwọ obinrin kan, Abieyinna Jaja, ṣọọbu mẹrin lo loun maa fi rẹnti fun un.

Bayii ni wọn lọkunrin onijibiti yii gba owo kaakiri lọwọ awọn eeyan lai jẹ pe wọn fa iṣẹ fifi ṣọọbu rẹnti le e lọwọ, Ọtunba Stephen Ajọsẹ to nile ọhun si sọ fawọn ọlọpaa pe oun o tiẹ kofiri ẹ ri debii pe awọn jọ sọrọ, bẹẹ ni ko kowo kan foun.

Ẹsun mọkanla ọtọọtọ ni wọn ka si olujẹjọ yii lọrun, lara ẹ ni pe o lu jibiti, o pera ẹ ni ohun ti ko jẹ fawọn eeyan, o fẹtan gbowo lọwọ awọn ẹni ẹlẹni, o si tun jale.

Wọn lawọn ẹsun naa ta ko isọri ọọdunrun ati mẹrinla (314), isọri irinwo ati mọkanla (411) ati isọri kejidinlaaadọsan-an (168) iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko, ijiya to  jẹbi wọn.

Nigba ti wọn beere ọrọ lọwọ olujẹjọ, Ademọla loun o jẹbi awọn ẹsun wọnyi pẹlu alaye, n ladajọ Majisreeti naa ba ni ko sọ alaye ẹ di ọjọ mi-in na, o ni ki wọn ṣi tọju ẹ sahaamọ ọgba ẹwọn Kirikiri. Amọ o faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹlẹrii meji ti wọn gbọdọ ni iye owo kan naa lọwọ, ki wọn si jẹ oṣiṣẹ ijọba to ni dukia to tẹwọn sagbegbe kootu naa.

 

Leave a Reply