Faith Adebọla
Niṣe loju Adajọ Chizoba Orji tile-ẹjọ giga apapọ to fikalẹ sagbegbe Maitama, niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, kọrẹ lọwọ, baba agba naa ko rẹrin-in rara, tibinu-tibinu lo si fi paṣẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe kawọn agbofinro lọọ mu Alaga ajọ to n gbogun tiwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nni, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), Abdulrasheed Bawa, o ni ki wọn la a mẹwọn werewere, tori ajọ naa n tapa si aṣẹ ile-ẹjọ, oun o si ribi ti eto ijọba awa-ara-wa ti faaye gba igbakugba bẹẹ, o ni ki wọn lọọ fọkunrin naa pamọ sọgba ẹwọn Kuje, l’Abuja, titi ti ajọ EFCC yoo fi mu idajọ ile-ẹjọ ti wọn pa fun wọn lọdun mẹrin sẹyin, ṣẹ.
Bakan naa l’adajọ yii paṣẹ pe ki Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa, Alkali Baba, ri i daju pe wọn mu aṣẹ tile-ẹjọ naa pa yii ṣẹ lai sọsẹ, ki wọn fi pampẹ ofin gbe Bawa, tori oun ko ṣawada, ko si sẹni to ga ju ofin lọ.
Ninu iwe aṣẹ ile-ẹjọ ti adajọ naa buwọ lu lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ti wọn fi ẹda rẹ han ni kootu ọhun, lo ti ṣalaye pe lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2018, iyẹn nnkan bii ọdun mẹrin sẹyin, ni ile-ẹjọ giga Abuja kan ti paṣẹ fun EFCC pe ki wọn da ọkọ ayọkẹlẹ Range Rover ti wọn gba nidii olupẹjọ kan, Ọgagun Rufus Adeniyi Ojuawo, to ti figba kan jẹ alakooso agba nileeṣẹ awọn ọmoogun oju ofurufu ilẹ wa, pada, ki wọn si da ogoji miliọnu Naira ti wọn lawọn gbẹsẹ le lọwọ rẹ pada fun un, tori ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Ṣaaju, lọdun 2016, ni EFCC ti wọ Ojuawo lọ sile-ẹjọ giga kan niluu Nyaya, l’Abuja, wọn fẹsun kan an pe o gba abẹtẹlẹ ti iye rẹ jẹ ogoji miliọnu Naira lọwọ Ọgbẹni Hima Abubakar ti ileeṣẹ Societe D’Equipment Internationaux Nigeria Limited, wọn lara riba to gba ọhun ni ọkọ ayọkẹlẹ bọginni Range Rover Sport to fi n ṣẹsẹ rin, wọn lowo ọkọ naa to miliọnu mọkandinlọgbọn Naira.
Onidaajọ Muawiya Baba Idris lo gbọ ẹjọ naa fun ọdun meji, nigba to si di ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2018, Adajọ Idris ni olujẹjọ yii ko jẹbi, o ni EFCC ko ri ẹri to nilaari kankan mu wa lodi si ẹni ti wọn fẹsun kan, bẹẹ ojuṣe ẹni to ba fẹsun kan’ni ni lati fẹri to muna doko gbe ẹsun rẹ lẹsẹ, gẹgẹ bo ṣe wa ni isọri kọkanlelaaadoje iwe ofin ijẹrii nilẹ wa. Adajọ ni ‘o ni ọ jọ pe, o da bii pe’ ni agbẹjọro EFCC n sọ nile-ẹjọ, kootu ki i si i gbe idajọ kari ifura odi lasan, tori ẹ, wọn da ẹjọ naa nu bii omi iṣanwọ, wọn ni b’ẹbiti o ba peku, aa fẹyin fẹlẹyin ni, tori ẹ, ki wọn da mọto ati owo olujẹjọ pada fun un, ko maa lọ sile ẹ.
Lọọya Ojuawo, Ọgbẹni R. N. Ọjabo, ṣalaye pe, latigba naa ni EFCC ti ta ku, wọn ko mu aṣẹ ile-ẹjọ yii ṣẹ tori idajọ naa ko gbe wọn, wọn ko pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn ko si mu ẹri mi-in jade, sibẹ wọn kọ lati da nnkan ini onibaara oun pada fun un lati bii ọdun mẹrin sẹyin, niṣe ni wọn n foni-donii, fọla-dọla fawọn, eyi lo mu ki Ojuawo tun kọri si kootu lati lọọ fẹjọ EFCC sun, to si pe wọn lẹjọ.
Eyi lo mu ki Adajọ Orji paṣẹ ki wọn lọọ mu ẹnikẹni to ba jẹ olori ajọ EFCC lọwọlọwọ, ki wọn sọ ọ sẹwọn, tori iwa irufin gbaa lo jẹ kile-ẹjọ paṣẹ, ki ajọ kan si kọti ikun si i. Adajọ ni ọjọ ti wọn ba da mọto atowo olowo yii pada ni ki wọn too ṣi Alaga EFCC silẹ lẹwọn.